Ifa lo yan emi o, ọba to ba ni Ifa kọ lo yan oun ko mọ ohun to n sọ ni-Ọlọta Odo-Ọwa 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọba Joshua Adeyẹmi Adimula, Ọlọ́tà ti ilu Odò-Ọwá, nipinlẹ Kwara, ti sọ pe Ifa lo yan oun sipo, ki i ṣe gomina, ta a ba ri ọba kan nilẹ Yoruba to ni Ifa kọ lo yan oun ko mọ ohun to n sọ ni.

Kabieesi sọrọ yii lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrin, oṣu Keje yii, niluu Odò -Ọwá, ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu ALAROYE, lasiko ti wọn ṣayẹyẹ ọdun ijẹsu tọdun 2023 yii.

Ọba Joshua Adimula sọ pe awọn gomina kọ ni wọn n yan ọba, wọn kan maa buwọ lu iyansipo naa lẹyin tawọn afọbajẹ ba ti fi orukọ ọmọ oye sọwọ si wọn ni.

Ọlọta ni, “Ọdun kẹjọ mi ree lori apere, emi o du oye, Ifa lo yan mi, Ifa ni yoo tọka ọmọ oye, ọba kọba to ba ni Ifa kọ lo yan oun nilẹ Yoruba, ko mọ ohun to n sọ. Lẹyin ti Ifa ba ti mu ọmọ oye tan, awọn afọbajẹ yoo forukọ ṣọwọ si ijọba ibilẹ, ijọba ibilẹ ni yoo waa fi orukọ naa ṣọwọ si gomina fun ibuwọlu patapata, ki wọn to waa kede si gbangba.

‘‘Irọ to jinna sootọ ni Ọba Oluwoo tiluu Iwo, Ọba AbdulRasheed, sọ, pe ẹni ti gomina ba mu ni Ọlọrun ti yan lati jẹ ọba. Ko si ọba kankan nilẹ Yoruba ti yoo sọ pe Ifa mu oun.

“Oluwoo n fi awọn ọrọ rẹ yẹpẹrẹ aṣa Yoruba ni.”

Kabiyesi tẹsiwaju pe awọn ṣe ayẹyẹ ọdun ijẹsu, nibi ti Olori yoo ti mu iṣu tuntun lọ si ọja lati fi han pe wọn fẹẹ bọ si ọdun tuntun, tori pe agbẹ ni iṣẹ ti wọn yan laayo lati ibẹrẹ pẹpẹ, ti ọdun ba ti ku ọsẹ meji ni Kabiyesi ko ni i le jade kuro niluu, ti wọn a maa ṣe oniruuru etutu, ti ọba yoo si maa lọọ gbe ida fun awọn to n bọ ogun tori pe lasiko ọdun yii ni wọn maa n bọ Ogun, ti wọn si wure fun gbogbo ilu, ki ilu le tuba-tuṣẹ.

 

Leave a Reply