Jamiu Abayọmi
Gbajumọ oṣere tiata Yoruba nni, Ẹniọla Badmus, ti gbogbo eeyan tun mọ si Wule Bantu, ti kegbajare si gbogbo ọmọ Naijiria lati gba oun lọwọ ọkunrin kan to ti n dunkooko iku mọ oun lati bii ọjọ mẹta kan sẹyin bayii.
Oju opo Twitter rẹ lo fi fidio naa si, to ti n ṣalaye bi ọkunrin kan ṣe n fi nọmba kan tẹ atẹjiṣẹ iku soun latigba toun ti gbe ọmọbinrin kan to ba a lorukọ jẹ lọ sile-ẹjọ, tiyẹn si gbabẹ rẹwọn ọdun mẹta he.
Ibẹ ni oṣerebinrin yii ti n bẹ gbogbo ọmọ Naijiria lati ba a pe nọmba naa, ki wọn si faye ni ọkunrin naa lara.
O ni, “ Ẹ jọwọ, ẹyin eeyan, ẹ ba mi pe ọkunrin yii ki ẹ si faye ni i lara, nitori pe o ti n dunkooko iku mọ mi bayii.”
Ninu fọnran naa lo ti n fẹdun ọkan rẹ han lori bi awọn eeyan ṣe maa n bu u. “Mi o mọ idi tawọn eeyan fi maa fẹ lati baayan lorukọ jẹ, koda lasiko idibo to kọja, awọn kan tun n fi ẹya ara mi bu mi, nitori ẹgbẹ oṣelu ti mo ṣe atilẹyin fun, ko yẹ ko ri bẹẹ, eeyan ẹlẹran ara lawa gbajumọ naa, bo tilẹ jẹ pe mi o ki n kọbi ara si bi awọn eeyan ṣe maa n tabuku mi, ṣugbọn ti ibanilorukọjẹ yii, mi o fara mọ ọn, eyi yoo si jẹ arikọgbọn fun awọn to ba ṣi fẹẹ ṣe nnkan to ba jọ bẹẹ lọjọ iwaju”.
Tẹ o ba gbagbe, ọmọbinrin kan, Okoye Blessing Nwakego, tawọn kan tun mọ si Ego, to maa n ṣe fidio loju opo Tiktok, lo ko ara rẹ sinu iyọnu latigba to ti pe Ẹniọla ni (PIMP ), eyi to tumọ si ẹni to maa n fi awọn ọmọbinrin ṣowo nabi, to maa n gbe wọn fun ọkunrin, ti yoo si gba ipin tirẹ ninu owo ti wọn ba pa ninu iṣẹ aṣẹwo naa.
Oṣerebinrin yii fọrọ naa to awọn agbofinro leti, ti wọn si wọ ọmọbinrin naa lọ sile-ẹjọ giga ipinlẹ Eko l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ keji, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, nibi ti adajọ ti ran an sẹwọn ọdun mẹta tabi ko san owo itanran ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira (N150,000) fun apapọ gbogbo ẹsun ti wọn fi kan an.
Latigba naa si ni ọpọ eeyan ti n fi ero wọn han lori ohun ti Ẹniọla ṣe yii lori ayelujara, bi a ti ri awọn to n sọ pe ohun to ṣe dara, bẹẹ naa lawọn kan n sọ pe ọwọ agbara lo n lo fun ọmọbinrin ọhun, lara awọn to koro oju si nnkan to ṣe naa ni ọmọkunrin to n tẹ atẹjiṣẹ iku si i yii.