Adewale Adeoye
‘Eeyan meloo gan-an lawọn ṣọja ati ọlọpaa fẹẹ yinbọn pa’ lawọn olugbe agbegbe kan bayii ti wọn n pe ni Kpansia niluu Yenagoa, nipinlẹ Bayelsa, fọrọ ọhun ṣe nigba ti ogunlọgọ wọn tu sita, ti wọn si doju kọ ile ikẹrupamọsi kan ti wọn sọ pe o jẹ tijọba ipinlẹ naa, nibi ti wọn ko awọn ounjẹ oniruuru palietiifu ti wọn gbagbọ pe o ti yẹ kawọn alaṣẹ ijọba pin fawọn araalu gbogbo ti ebi n pa, ṣugbọn ti wọn ko pin in si.
ALAROYE gbọ pe ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 yii, lawọn araalu naa fibinu lọọ jalẹkun ile ikerupamọsi naa, ti kaluku wọn si n gbe ohun tọwọ wọn ba to, ti wọn si n dori kọ ile wọn loju-ẹsẹ.
Ọpọ lara awọn ti wọn hu iwa laabi naa ni wọn n sọ pe ilu ko fara rọ mọ fawọn latigba tijọba Aarẹ Tinubu ti yọ owo iranwọ lori epo bẹntiroolu, ni gbara to dori aleefa lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii. Wọn ni ati-jẹ di ogun, bẹẹ ni awọn ko riṣẹ ṣe nitori ọpọ ibi ti awọn ti n ṣiṣẹ ni wọn ti le awọn danu, wọn ni awọn ko le ri owo oṣu san fawọn. Bẹẹ lawọn niyawo, tawọn si ni ọmọ nile tawọn maa tọju. Eyi lo sun awọn debi iwakiwa naa.
Iroyin kan ta a ko ti i fidi rẹ mulẹ sọ pe palietiifu tawọn araalu naa lọọ ji ko jẹ ti eyi tawọn ẹlẹyinju aanu ọmọ orileede wa kan ko silẹ fawọn ti ẹkun omi n yọ lẹnu lọdun 2022 to koja yii. Bẹẹ lawọn alaṣẹ ilu naa ko ti i sọrọ lori iṣẹlẹ naa latigba tawọn kan ti lọọ fipa ja ile ikẹrupamọ si naa.
Ṣugbọn ohun tawọn kan n sọ ni pe ibaa jẹ tawọn ti ẹkun omi n yọ lẹnu, ibaa si jẹ eyi tijọba ko ranṣẹ, araalu naa lo ni gbogbo rẹ, ki i ṣe ijọba. Idi ti wọn fi ko o pamọ ti wọn ko pin fẹnikan, ti ebi si n pa awọn ku lọ niluu ko ye ẹnikẹni.