Emefiele ti rogo o, ile-ẹjọ ni ki wọn maa gbe e lọ sọgba ẹwọn Kuje!

Faith Adebọla

Lai fi ti bi wọn ṣe yọnda beeli fun un lọsẹ to kọja yii pe, ile-ẹjọ giga apapọ kan to filu Abuja ṣe ibujokoo ti ni ki wọn maa gbe ọga agba banki apapọ ilẹ wa tẹlẹ, Alagba Godwin Emefiele, lọ sọgba ẹwọn Kuje, l’Abuja.

Lowurọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kọkanla yii, ni ọkunrin to ti n kawọ pọnyin rojọ lori awọn ẹsun iwa ọdaran kan tijọba apapọ fi kan an tun fara han niwaju Onidaajọ Hamza Muazu, eyi ti ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo ilu mọkumọku, Economic and Financial Crimes Commission, (EFCC), wọ ọ lọ.

Ẹsun tuntun mẹfa ọtọọtọ ni wọn fi kan Emefiele. Lara rẹ ni pe o ra awọn nnkan eelo ati dukia kan lọna aibofin mu, to si jẹ pe lasiko naa lawọn owo tuulu-tuulu to to biliọnu kan ati miliọnu lọna ọgọrun-un mẹfa Naira poora ni koto ọba.

Ogun lawọn ẹsun ti EFCC ti kọkọ lawọn fẹẹ ka si baba agbalagba naa lẹsẹ, Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii, si ni igbẹjọ rẹ iba waye, amọ latari iyanṣẹlodi ti ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ nilẹ wa gun le lọjọ Iṣẹgun ati Ọjọruu ọhun, igbẹjọ rẹ ko le waye. Eyi lo mu ki wọn sun ẹjọ naa si ọjọ Ẹti yii, ti olupẹjọ si ti din ẹsun naa ku si mẹfa.

Gẹrẹ ti wọn ka awọn ẹsun wọnyi si i leti tan, to si rawọ ẹbẹ pe oun ko jẹbi wọn, niṣe ni agbẹjọro rẹ, Amofin agba Matthew Burkaa ti dide, o ni onibaara oun ti kọwe ẹbẹ fun beeli, oun si fẹ ki kootu naa fountẹ jan an, amọ Amofin agba Rotimi Oyedepo, to n ṣoju fun EFCC ati ijọba apapọ to n ba Emefiele ṣẹjọ ta ko ẹbẹ rẹ yii.

Lẹyin ti Adajọ ti tẹti bẹlẹjẹ gbọ awijare ati atotonu tọtun-tosi, Muazu ni afi ki wọn foun laaye lati ṣayẹwo daadaa si awọn iwe ati nnkan aritọkasi ti afurasi ọdaran yii ko kalẹ lati fi bẹbẹ fun beeli.

Tori bẹẹ, ile-ẹjọ naa paṣẹ pe ki wọn si taari Emefiele sọgba ẹwọn Kuje, titi di ọjọ kejilelogun, oṣu Kọkanla, iyẹn Ọjọruu, ọsẹ to n bọ, nigba naa ni ọkunrin yii yoo too gbọ ipinnu ile-ẹjọ lori beeli to beere fun ọhun.

Ẹ oo ranti pe latigba ti Aarẹ Bọla Tinubu ti le e kuro lori aga Ọga agba Central Bank of Nigeria, lọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni idaamu daabo ti de ba a. Latigba naa nijọba si ti n ba a ṣẹjọ.

Leave a Reply