Monisọla Saka
Oludije funpo gomina ipinlẹ Eko labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Action Democratic Congress (ADC), Ọgbẹni Funshọ Doherty, ti fẹsun kan Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, lori bi wọn ṣe n ṣe owo ilu, paapaa ju lọ owo awọn to n sanwo ori mọkumọku.
Latigba tọrọ naa ti lu si gbangba ni ẹnu ti n kun gomina yii lori awọn obitibiti owo ti wọn ti ṣeto silẹ fun oniruuru nnkan ti wọn fẹẹ ra si ọfiisi gomina, igbakeji rẹ ati ile ọba Eko ninu bọjẹẹti wọn.
Miliọnu meje aabọ Naira (7.5 million), ni gomina fi fẹẹ paarọ omi olooorun didun to wa lọọfiisi rẹ, bẹẹ ni wọn fẹẹ lo biliọnu mẹta Naira (3 billion), lati ra awọn faanu alatẹtan ti wọn maa n gbana si lara, si ọfiisi Ọbafẹmi Hamzat, ti i ṣe igbakeji rẹ.
Bakan naa ni wọn tun ni ojilenirinwo miliọnu Naira (440 million), ni ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Eko to n ri si ọrọ iṣẹ ode buwọ lu lati fi ra ọkọ ayọkẹlẹ bọginni akọ́tamì Lexus LX 600 Bulletproof, fun wọn lọọfiisi olori awọn oṣiṣẹ.
Yato si eyi, wọn tun pese miliọnu mejidinlogun ataabọ (18.5 million), fun ọfiisi olori oṣiṣẹ lati fi ra adiẹ aaye bii ẹgbẹrun meji, ki wọn si pin in kaakiri ijọba ibilẹ ati wọọdu to wa nipinlẹ Eko.
Siwaju si i, miliọnu mejilelaaadọjọ Naira (152 million), ni Gomina Sanwo-Olu buwọ lu pe ki wọn fi tun omi inu aafin Iduganran ti Ọba ilu Eko ṣe. Bẹẹ ni wọn yoo fi ọrinlelẹẹẹdẹgbẹta ati miliọnu Naira kan (581 million), tun ile ijọsin St. Andrew’s Anglican Church, Oke Popo, niluu Eko ṣe. Lẹyin naa ni wọn tun buwọ lu miliọnu lọna ọgbọn Naira fun igbakeji gomina eyi ti iyawo rẹ yoo maa fun awọn ọmọ bibi ilu Eko, loṣooṣu. Ati miliọnu lọna ọgbọn Naira mi-in fun eto ironilagbara nipinlẹ Eko.
Ninu ọrọ Funsho Doherty lo ti ṣalaye pe oun ti kọ lẹta ita gbangba si Gomina Sanwo-Olu lati ṣatunṣe sawọn iṣẹ akanṣe ọhun.
“Mo ṣẹṣẹ kọ lẹta ita gbangba si gomina tan ni lori awọn iṣẹ akanṣe fun idaji ati ida kẹta ọdun 2023 yii, mo si ti to awọn ọrọ to nilo ayẹwo ati atunṣe silẹ fun wọn. Nitori o ṣe pataki lati lo ọrọ̀ ilu bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ, agaga niru akoko ta a wa yii.
”Gẹgẹ bi ọkunrin kan, Dokita Abimbọla Ọyarinu, ṣe sọ ọ ninu iwe iroyin Daily Trust, o ni o ba ni lọkan jẹ pe ijọba lo n jẹ eyi to ju ninu igbadun, nigba ti wọn n sọ fawọn eeyan lati maa fara da iya to wa nita lọ. Amọ o ni atubọtan nnkan tawọn ọmọ Naijiria fọwọ ara wọn fa ni wọn n jẹ lọwọ bayii’’.
Doherty sọrọ siwaju si i pe lododo, awọn eeyan loun ri ba wi dipo ijọba. Nitori awọn eeyan o le jẹun bi wọn ṣe fẹ mọ. Bẹẹ ni ki i ṣe gbogbo igba ni wọn le maa bu ijọba, nitori ko si ayipada lati ọdun ti wọn ti n ṣe bẹẹ.
“Dipo ka a pariwo fun ijọba lori awọn nnkan amayedẹrun ti wọn kọ ti wọn ko ṣe, eṣu naa la maa n di ẹru yii le lori, nitori ọrọ ẹsin ati ti eto iṣejọba wa lara nnkan ti wọn fi n gba awọn ọmọ Naijiria.
Abi bawo leeyan ṣe maa fi miliọnu meje Naira tan yanyan ra nnkan olooorun didun sinu ọfiisi rẹ, nigba tawọn to n ṣejọba le lori n daamu ki wọn too rounjẹ jẹ”.