Adewale Adeoye
Gbajumọ oṣerebirin ilẹ wa nni, Ọmọwumi Ajiboye, ti sọ pe ko si ọrọ ifẹ ikọkọ kankan laarin oun ati ọga awọn onimọto niluu Eko, Ọgbẹni Musiliu Akinsanya, tawọn eeyan tun mọ si MC Oluọmọ rara.
O sọrọ ọhun di mimọ ni idahun si ẹsun agbere kan tawọn ololufẹ rẹ fi kan an pe o n fẹ ọga awọn onimọto ọhun ni ko ṣe bọwọ fọkunrin to bimọ fun toun naa jẹ oṣere, iyẹn Ṣẹgun Ogungbe, lasiko ayẹyẹ aṣekagba inawo eto isinku mama rẹ to waye niluu Oṣogbo lọsẹ to kọja yii.
Ninu fidio ode ariya naa lawọn eeyan ti ri Ṣẹgun Ogungbe ti i ṣe ọkọ Wumi tẹlẹ, nibi to ti n nawo nibi ayẹyẹ ti iyawo rẹ tẹlẹ ọhun n ṣe, ṣugbọn ti Wumi ko tiẹ wo ibi to wa rara, ti KWAM 1, iyẹn olorin ti wọn pe sode ọhun ko tiẹ ki Ṣẹgun Ogungbe rara.
Atẹjade kan ti Wunmi gbe jade lori iṣẹ̀ẹ ọhun lo ti sọrọ lori ẹsun ti wọn fi kan an pe ko sifẹẹ ikọkọ kankan laarin oun ati ọga awọn onimọto ọhun rara gẹgẹ bi awọn kan ṣe n gbe e pooyi ẹnu kiri bayii.
O ni, ‘Bi mi o ba sọrọ, ko daa, ohun ti ma a si sọ ni pe mi o fẹ MC Oluọmọ rara o, ko si ibaṣepọ ikọkọ kankan laarin wa, alaaanu mi ni, ẹni to n ṣaanu mi nigba gbogbo ni. Ko sẹni ti ko mọ pe mo gbajumọ iṣẹ ọwọ mi daadaa, mi o si ni i waa laju silẹ kawọn kan waa fọrọ ẹnu buruku wọn baye mi jẹ nipa bi wọn ti ṣe n sọ ohun toju wọn ko to bayii nipa mi.
‘‘Ṣaaju akoko ode ariya yii ni ọba fuji iyẹn Wasiu Ayinde KWAM 1, ti gba lati waa kọrin nibi ode mi yii, MC Oluọmọ si ni baba isalẹ ẹgbẹ alaadani kan ti mo wa, ko sohun to buru nibẹ bi mo ba fiwe pe baba isalẹ ẹgbẹ yii sode inawo mi. Loootọ, MC Oluọmọ gbiyanju, o fun mi lowo fun ti inawo ọhun, ṣugbọn ko sifẹẹ ikọkọ kankan laarin emi pẹlu rẹ.
‘‘Mi o nifẹẹ ikọkọ pẹlu rẹ ki n too ṣe inawo mi, mi o nifẹẹ ikọkọ kankan pẹlu rẹ lakooko inawo mi, bẹẹ ni ko le sifẹẹ ikọkọ kankan laarin wa lẹyin inawo mi yii. Alaaanu mi lasan ni, baba isalẹ ẹgbẹ mi lasan ni. Owo to fun mi, niṣoju gbogbo ọmọ ẹgbẹ mi lo ti fun mu, ki i ṣe pe o da pe mi si kọrọ ko too fun mi.
‘‘O ṣe waa jẹ pe gbogbo aṣeyọri mi pata ni wọn n waa sọ pe MC Oluọmọ lọwọ ninu rẹ bayii, emi paapaa ki i ṣe ọlẹ tẹlẹ kẹ, bi mo ṣe dakẹ rọrọ bii odo, ki i ṣe pe mi o le sọrọ, tabi pe ẹru ija lo n ba mi. Emi Ọmọwunmi Ajiboye n fi asiko yii sọ fawọn ẹni to ba leti ki wọn gbọ pe ko sifẹẹ ikọkọ kankan laarin emi pẹlu MC Oluọmọ rara.’’