Aṣiri tu! Ajulọ ni ayederu ibuwọlu Akeredolu lawọn ọmọlẹyin rẹ fi n ṣe oriṣiiriṣii nnkan

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Agba agbẹjọro lorilẹ-ede yii, Amofin agba Kayọde Ajulọ, ti fẹsun kan awọn ọmọlẹyin Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, pe ayederu ibuwọlu rẹ ni wọn n lo lati fi ṣe ọpọlọpọ nnkan ti wọn n ṣe latigba ti ko ti si nile.

Ajulọ ninu ọrọ to sọ lasiko to n dahun awọn ibeere lori tẹlifisan Arise, to wa niluu Eko, ni ki i ṣe ifasẹyin kekere lo ba ipinlẹ Ondo lati inu oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, ti Aketi ko ti roju raaye ṣakoso nitori ara rẹ ti ko ya.

O ni ko si ani-ani pe awọn eeyan kan ti ja ijọba ipinlẹ Ondo gba lọwọlọwọ, niwọn igba ti Akeredolu ti kuna lati gbe ijọba fun Igbakeji rẹ, Lucky Ayedatiwa, gẹgẹ bii ilana ofin.

O ni ohun to wa ninu iwe ofin ni pe ki Igbakeji gomina maa ṣakoso nigbakuugba ti ọga rẹ ko ba si ni arọwọto fun idi kan tabi omiiran, ati pe ohunkohun to ba ti lodi si igbesẹ yii ko bofin mu rara labẹ bo ti wu ko ri.

Ajulọ ni: ‘’Awọn iwe aṣẹ kan ti wọn n fi sita lọwọlọwọ lorukọ gomina pẹlu ibuwọlu rẹ mu ifura nla lọwọ, nitori ọna wo lẹni tawọn araalu ko mọ ibi to wọlẹ si yoo fi waa maa buwọ lu iwe?

Mo gbiyanju lati ṣe ayẹwo finnifinni si ọkan ninu awọn iwe ọhun ti wọn mu wa si ọfiisi mi laipẹ yii, nigba ti mo si wo o daadaa gẹgẹ bii aṣewadii aladaani, mo ri i daju pe ayederu ni, ṣe ni wọn ṣe ẹda ibuwọlu Arakunrin. Nigba ti mo si beere lọwọ awọn to mu kinni ọhun wa, titi ni wọn n ti ọrọ naa sira wọn, ti wọn si n tọka si awọn eeyan kan pe awọn ni wọn ṣe agbatẹru rẹ.

Ohun ti mo le fọwọ rẹ sọya ni ibamu pẹlu iṣẹ amofin ti mo n ṣe ni pe awọn Kọmiṣanna bii marun-un ni wọn lawọn kọ awọn iwe ibeere kan si gomina, ti wọn si ni wọn ti da awọn iwe naa pada pẹlu ibuwọlu rẹ.

Nigba ti mo wo awọn ibuwọlu naa si awọn to ti wa lọdọ mi tẹlẹ lasiko ti Gomina Akeredolu wa nile, mo ri i daju pe ayederu patapata ni, nitori wọn yatọ sira wọn, wọn ko bara mu, mo le fọwọ rẹ sọya pe wọn ki i ṣe ti gomina rara.

Kọmiṣanna feto ifitonileti ati ilanilọyẹ nipinlẹ Ondo, Abilekọ Bamidele Ademọla-Ọlatẹju, lo kọkọ sọrọ nipa ẹsun ọhun lasiko to n dahun ibeere awọn oniroyin kan lọfiisi gomina l’ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kejila, ta a wa ninu rẹ yii, o ni bo tilẹ jẹ pe oun ko le sọ ni pato bi ọrọ naa ṣe jẹ, amọ oun ko ri iyatọ kankan ninu ibuwọlu Aketi nigba to wa nile atawọn ibuwọlu rẹ lati igba ti ko ti si nitosi mọ.

Akọwe iroyin fun gomina, Richard Ọlatunde, ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ karun-un, oṣu Kejila, ọdun 2023 ta a wa yii, ni idunnu awọn ọmọlẹyin Aketi ni yoo jẹ ti wọn ba le ṣe iwadii ẹsun yii daadaa, ki wọn si fiya jẹ ẹni ti aje iwa ibajẹ iṣẹlẹ naa ba ṣi mọ lori labẹ ofin.

Ọlatunde ni ẹsun yii ko ti i lẹsẹ nilẹ rara titi di igba ti iwadii yoo fi fidi rẹ mulẹ pe bẹẹ lọrọ ọhun ri. O ni awọn to mọ bi iroyin ayederu ibuwọlu Gomina Akeredolu ṣe jade gan-an ni ọbayejẹ ti wọn wa nidii iṣẹ ibi naa.

Obinrin naa ni oun ko nigbagbọ ninu ahesọ to n ja ran-in nilẹ naa, nitori Gomina Akeredolu nikan lo le sọ boya awọn kan ti ṣe ẹda ibuwọlu oun tabi bẹẹ kọ.

 

Leave a Reply