Wahala ree o! Awọn akẹkọọ mejidinlogun jẹ majele ninu ounjẹ nileewe l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

O kere tan, awọn akẹkọọ mejidinlogun ti  ileewe St James Primary School B, ni Ọ̀wọ́ọ̀pẹ niluu Oṣogbo, ni wọn di ero ileewosan lọsan-an ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanla, oṣu Kejila, ọdun yii.

Majele inu ounjẹ, (food poisoning), la gbọ pe o gbe awọn ọmọ naa de ileewosan aladaani kan niluu Oṣogbo.

Awọn olounjẹ ọfẹ ti ijọba ipinlẹ Ọṣun gba sileewe naa la gbọ pe wọn fun awọn akẹkọọ ni irẹsi ati ẹyin sise lasiko isinmi ounjẹ lọjọ naa.

Ṣugbọn bi awọn ọmọ aa nṣe dele ni wọn bẹrẹ si i yagbẹ, ti wọn si n bi. Bayii ni ariwo ta, ti onikaluku si n gbe ọmọ rẹ lọ sileewosan.

Ninu fọnran fidio kan to n lọ kaakiri ni obinrin kan ti sọ pe bi ọmọ oun ṣe de lati ileewe loun ṣakiyesi pe oorun ẹyin to ti dobuu lo n jade lẹnu rẹ.

Latari iṣẹlẹ yii ni Gomina Ademọla Adeleke fi paṣẹ pe ki iwadii kikun bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa. Ninu atẹjade kan latọwọ kọmiṣanna fun eto iroyin, Oluọmọ Kọlapọ Alimi, lo ti sọ pe gbogbo awọn iya olounjẹ naa ni yoo wi tẹnu wọn lori iṣẹlẹ ọhun.

Alimi ṣalaye pe gbogbo nnkan ti wọn nilo lati le jẹ ki wọn fun awọn akẹkọọ ni ounjẹ to peregede nijọba ti pese fun wọn, o si ni ki wọn dawọ fifun awọn akẹkọọ naa lounjẹ titi digba ti abọ iwadii yoo fi pari.

O ni ijọba ti san owo ti awọn ileewosan fi ṣetọju awọn akẹkọọ naa, o si ke si awọn araalu lati ma ṣe bẹru nitori iṣẹlẹ naa.

Leave a Reply