Ere agbere: Ẹ wo ohun tawọn akẹkọọ Fasiti Kogi ṣe fun olukọ wọn

Faith Adebọla

 Olukọ kan ni fasiti ijọba apapọ, Federal University to wa niluu Lọkọja, nipinlẹ Kogi, ko ni i gbagbe bawọn akẹkọọ rẹ ṣe foju ẹ ri mabo lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, latari bi wọn ṣe fẹsun agbere kan an, ti wọn si tori ẹ da sẹria fun un. Wọn bọ aṣọ ati ṣokoto to wọ nita gbangba, kidaa pata nikan to wọ bii awọtẹlẹ lo ku sidii ẹ, ni wọn ba fa a le awọn agbofinro lọwọ.

Lẹkiṣọra fasiti ọhun ti wọn ko darukọ ẹ ni wọn lo n kọ awọn akẹkọọ ni ẹka imọ ede oyinbo, English Language Department, amọ bo ṣe n kọ wọn lẹkọọ ọhun ni ko tun jẹ kawọn akẹkọọ-binrin ẹka ọhun rimu mi, niṣe lo n fi iṣekuṣe lọ wọn, to si n dunkooko mọ wọn nigba gbogbo, ki wọn le gba fun un lati yan wọn lọrẹẹ ikọkọ.

Wọn lo pẹ ti afurasi ọdaran yii ti maa n wa awọn akẹkọọ-binrin fasiti ọhun lọ si ilegbee wọn to wa ni Adankolo mini Campus, nibi ti wọn lo ti fẹyin awọn kan lara wọn balẹ ni dandan.

Eyi lo bi awọn kan ninu lara awọn akẹkọọ ọhun ti wọn fi dọdẹ rẹ, ti wọn si gẹgun de e, lati fiya jẹ ẹ nigbakuugba to ba tun wa si ositẹẹli wọn bo ṣe maa n ṣe.

ALAROYE gbọ pe lọjọ Ẹti, Furaidee, ọhun ti ẹlẹkẹru tun de, niṣe lawọn akẹkọọ naa ṣuru bo o, ti wọn bẹrẹ si i ho le e lori, oriṣiiriṣii ọrọ eebu ati abuku si ni wọn sọ si i. Lẹyin eyi ni wọn da a kunlẹ, wọn bọ ẹwu ọrun rẹ, wọn si bọ ṣokoto rẹ titi dori pata, ọpẹlọpẹ awọn ọlọdẹ ti wọn n ṣọ ọgba naa, awọn ni wọn tara ṣaṣa ko saarin awọn akẹkọọ naa, ti wọn ko si gba wọn laaye lati rin olukọ yii nihooho, ki wọn too mu un lọ lẹyin-ọ-rẹyin.

Ohun ta a gbọ ni pe nigba ti wọn n fọrọ wa a lẹnu wo, lẹkiṣọra yii jẹwọ pe loootọ loun yan awọn kan lara awọn akẹkọọ-binrin naa lọrẹ, amọ o tun darukọ awọn olukọ ẹlẹgbẹ rẹ, titi dori ọga agba ẹka wọn, iyẹn HOD (Head of Department), o ni gbogbo wọn ni wọn maa n bẹ oun lọwẹ lati jẹ ki akẹkọọ ti wọn n yan lọrẹẹ paasi ẹkọ English toun n kọ wọn, kọntiraati ti wọn si n gbe foun yii, ibalopọ ni wọn fi n san an, tori bi akẹkọọ-binrin kan ba ṣe ṣe kurukẹrẹ pẹlu olukọ to yan an lọrẹẹ to lo maa pinnu bo ṣe maa paasi si.

Ṣa, ni bayii, lẹkiṣọra yii ti wa lakolo awọn agbofinro, Agbẹnusọ fun fasiti ọhun, Ọgbẹni Daniel Iyke, si ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O ni, ‘’Fasiti wa ni ilana ta a fi n bojuto iru ọrọ bayii. Iṣẹlẹ yii ti de etiigbọ ọga ọgba, iyẹn Vice-Chancellor wa, wọn si ti gbe igbimọ kan dide lẹyẹ-o-sọka lati ṣewadii, ki wọn si jabọ nipa ẹ. Ti esi iwadii wọn ba ti jade, a o gbe igbesẹ to tọ, to si bofin mu. Gbogbo nnkan ti mo ṣi le sọ lori ọrọ yii lasiko yii niyẹn.” Gẹgẹ bo ṣe wi.

Leave a Reply