Ijọba apapọ fẹẹ dawọ tita afẹfẹ idana s’Oke-Okun duro

Adewale Adeoye

Lojuna ati le jẹ ki nnkan dẹrun fawọn araalu, paapaa ju lọ bi owo afẹfẹ idana ‘Liquefied Petroleum Gas’ (LPG), tawọn araalu n lo ṣe n fojoojumọ gbowo lori bayii, ijọba orileede yii ti sọ pe awọn maa too dawọ tita afẹfẹ idana ọhun s’Oke-Okun duro, ki owo ọja naa le wa silẹ daadaa, kawọn araalu le lanfaani lati maa ra a lowo pọọku fun lilo.

Wọn sọ pe bẹrẹ lati ọjọ kin-in-ni, oṣu Kọkanla, ọdun yii, awọn ko ni i faaye gba awọn oniṣowo ọja naa lati maa gbe e lọọ s’Oke-Okun mọ gẹgẹ bi wọn ṣe n gbe e lọ tẹlẹ. Wọn ni igbesẹ naa maa jẹ ki owo ọja ọhun wa silẹ jọjọ, tawọn araalu si maa lanfaani lati ri i ra lowo pọọku, niwọn igba to ba ti wa lọja lọpọ yanturu.

Minisita ọrọ epo bẹntiroolu lorileede yii, Ọgbẹni Ekperikpe Ekpo, lo sọrọ ọhun di mimọ nibi ipade pataki kan to waye l’Abuja laipẹ yii. Nibi ipade naa lo ti sọ pe, bẹrẹ lati ọjọ kin-in-ni, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ijọba apapọ maa bẹrẹ si i fopin si tita afẹfẹ idana silẹ okeere, kowo ọja naa le wa silẹ laarin ilu.

O ni bi owo afẹfẹ idana ṣe n fojoojumọ gbowo lori ko dun mọ ijọba ninu rara, ti wọn si n wa gbogbo ọna lati jẹ ki owo ọja naa walẹ daadaa. Lara ọna to ni wọn le gba ni pe ki wọn dawọ tita a silẹ okeere duro lẹsẹkẹsẹ.

O fi kun un pe ijọba n ṣiṣẹ takuntakun labẹnu bayii lati jẹ kawọn ohun eelo tawọn ileeṣẹ ti wọn fi n ṣe afẹfẹ idana naa maa wa lọpọ yanturu nilẹ wa, ki idiwọ kankan ma baa waye fun wọn mọ.

Leave a Reply