Jọkẹ Amọri
Awọn alagbata epo gbe Dangote lọ si kootu, wọn ni dandan ni kawọn maa ra epo l’Oke-Okun
O da bii pe aṣiri kan wa ninu ọrọ epo bẹntiroolu ti ileeṣẹ to n mojuto ọrọ epo nilẹ wa, NNPCL atawọn alagbata epo ni afi ki awọn maa lọọ gbe wa lati Oke-Okun ti wọn ko ti i nigboya lati sọ fun ẹnikẹni, pẹlu bi wọn ṣe gbe ileeṣẹ Dangote lọ si kootu bayii pe afi dandan ki awọn maa lọọ gbe epo wa lati Oke-Okun, dipo ki awọn maa ra eyi ti Dangote n ṣe nilẹ wa.
Ni bayii, awọn ẹgbẹ alagbata epo kan ti gba ile-ẹjọ giga kan niluu Abuja lọ, nibi ti wọn ti sọ pe ki ile-ẹjọ fagi le ẹjọ ti Dangote pe ta ko awọn atawọn mi-in, ninu eyi ti ileeṣẹ to n sakoso ọrọ epo nilẹ wa, Nigerian Midstream and Downstream Petroleum Regulatory Authority (NMDPRA) wa, lọjọ kẹfa, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, pe ki awọn yee lọọ gbe epo wa lati Oke-Okun, ki awọn maa ra a nileeṣẹ ifọpo ti Dangote ṣẹṣẹ da silẹ.
Awọn alagbata epo ọhun, ninu eyi ti ileeṣẹ AYM Shafa Limited, A.A. Rano Limited ati Matrix Petroleum Limited, wa ni wọn sọ ninu iwe ẹjọ ti wọn pe ta ko ẹjọ ti ileeṣẹ Dangote pe pe bi ile-ẹjọ ba gba ileeṣẹ Dangote laaye lati maa gbe epo fun awọn alagbata epo ni Naijiria, iparun nla lo maa mu wa fun ileeṣẹ epo lorileede wa.
Lara awijare wọn ninu ẹjọ ti wọn pe lọjọ karun-un, oṣu yii, ni pe ileeṣẹ ifọpo Dangote nikan ni yoo maa da ṣe epo.
Ninu ẹjọ ti ileeṣẹ Dangote pe naa lo ti sọ pe ki ile-ẹjọ sọ pe igbesẹ to lodi sofin to ni ileeṣẹ to n sakoso tita ati gbigbe epo wọle nilẹ wa (NMDPRA)gbe lati fun awọn alagbata niwee aṣẹ lati maa lọọ gbe epo wa lati ilẹ okeere.
Ileeṣẹ naa ni idi kan pataki ti wọn fi le fun awọn alagbata niru iwe aṣẹ bẹẹ lati maa lọọ gbe epo ni bi ọwọngogo epo ba wa nilẹ wa, eyi ti ko si ṣẹlẹ rara.
Olupẹjọ naa sọ pe ki ile-ẹjọ paṣẹ pe ileeṣẹ to n sakoso tita ati gbigbe epo wọle nilẹ wọn ṣe lodi si ojuṣe wọn labẹ ofin to de ọrọ epo bẹntiroolu nilẹ wa, eyi to sọ pe ki wọn maa ṣatilẹyin fun ileesẹ ifọpo ti wọn ba da silẹ nilẹ wa gẹgẹ bii iru eyi ti awọn ni yii.
Ṣugbọn ninu awijare wọn, awọn elepo naa ni Dangote ko pese epo to to lati lo nilẹ wa, bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ifọpo Dangote ti jade laimọye igba pe orileede Naijiria ko le lo epo ti awọn n fọ lojumọ kan tan.
Bakan naa ni wọn sọ pe awọn lẹtọọ lati gba iwe aṣẹ ti ileeṣẹ to n ṣakoso epo bẹntiroolu nilẹ wa fun awọn nitori awọn kun oju oṣuwọn, bẹẹ ni awọn si tẹle gbogbo ilana ati ofin to rọ mọ gbigba iwe aṣẹ naa ki wọn too fun awọn.
Wọn fi kun un pe iwe aṣẹ ti awọn gba yii ko ni ohunkohun i ṣe pẹlu ileeṣẹ ifọpo Dangote, awọn ko si di i lọwọ lati ta ọja tirẹ. Bakan naa ni wọn sọ pe bi ile-ẹjọ ba fun Dangote niru aṣẹ yii, yoo faaye gba a lati maa da epo ṣe, ti yoo si jẹ awọn nikan ni wọn yoo wa ọrọ epo ṣiṣe maya nilẹ wa, eyi ti wọn ni ko daa fun ọrọ aje wa, ti yoo si mu ipalara wa fun un pẹlu bi ojojo ṣẹ n ṣe ọrọ-aje ọhun.
Lara awijare wọn ni pe bi nnkan kan ba ṣẹ ileepo yii, iṣoro ati wahala nla ni yoo wa fun awọn ọmọ Naijiria nitori ko ni ibi to le tọju epo ti Naijiria le lo laarin asiko naa titi di bii ọgbọn ọjọ si.
Yatọ si eyi, wọn ni pẹlu bi ko ṣe si ẹri pe ileeṣẹ naa le pese epo to to fun Naijiria lati lo, ewu nla ni yoo jẹ fun orileede wa.
Wọn fi kun un pe ti kootu ba fi le dahun si ohun ti ileeṣẹ ifọpo Dangote n beere fun, a jẹ pe oju ileeṣẹ yii nikan ni orileede Naijiria yoo maa wo lori ọrọ epo.
Nigba ti o n ba ALAROYE sọrọ lori ọrọ naa, ọkan ninu awọn ọga to n ri si eto iroyin nileeṣẹ Dangote, Ọgbẹni Sunday Ẹsan, sọ pe awawi lasan ni gbogbo ẹjọ ti awọn alagbata epo yii n ro. O ni awọn eeyan naa ko ti i sọ ẹni ti wọn n ṣiṣẹ fun ati idi ti wọn fi n ṣe ohun ti wọn n ṣe yii, bo tilẹ jẹ pe fun ipalara awọn ọmọ Naijiria ati anfaani tiwọn nikan nim ti wọn ko si ro ewu ti igbesẹ ti wọn n gbe yii yoo mu ba ọrọ aje wa.
Ẹsan ni ọrọ yii ko fa ija rara, ki ileeṣẹ NNPCL tun awọn ileeṣẹ ifọpo ta a ni nilẹ wa ṣe, eyi ti yoo fun awọn araalu ni anfaani lati ra epo nibi to ba ti wu wọn, ti ko si ni i pe ẹni kan lo wa aṣẹ tabi idari epo mọya.
Nigba to n fesi lori bi wọn ṣe sọ pe ileeṣẹ ifọpo Dangote ko le pese epo to to lati lo fun Naijira, ọkunrin naa sọ pe irọ to jinna soootọ ni eleyii, nitori bii ọgbọn miliọnu lita ni ileeṣẹ ifọpo awọn n ṣe lojumọ, bẹẹ ni awọn ni agba epo ti awọn tọju epo bẹntiroolu to jẹ ẹẹdẹgbẹta miliọnu lita si lati lo lasiko idagiri, eyi ti awọn ọmọ Naijiria le lo fun bii ọjọ mejila. Bẹẹ lo ni iṣẹ ti n lọ bi oun ṣe n sọrọ yii, tawọn ti n ṣe awọn agba epo mi-in ti epo yoo fi le wa fun odidi ọgbọnjọ bi ohunkohun ba ṣẹlẹ.
Agbẹnusọ ileeṣẹ Dangote yii ṣalaye siwaju pe bii igba ti awọn eeyan naa ni ọkọ nilẹ, ti wọn n fọwọ komi ni ọrọ yii, nitori eeyan ko le ni ẹgbaa nile, ko tun maa wa ẹgbaa rode. Anfaani to pọ lo ni gbigbe epo nileeṣẹ Dangote yoo mu ba ọrọ-aje Naijiria. Yatọ si pe yoo pese iṣẹ fun awọn ọdọ ilẹ wa, yoo din ifowoṣofo ku nipa lilọọ gbe epo wa lati Oke-Okun. Bakan naa lo ni yoo mu ki owo Naira lagbara si i, nitori ko ni i si pe awọn eeyan n jijagudu lati wa owo Dọla kiri bi o ṣe wa lasiko yii mọ, niwọn igba to jẹ pe owo Naira ni a oo maa lo fun gbogbo idokoowo ti a ba fẹẹ ṣe.
O ni bi wọn ṣe pariwo titi lori ọrọ simẹnti niyẹn. Ọkunrin yii ni ka ranti pe ileeṣẹ Larfarge lo kọkọ bẹrẹ simẹnti ko too di pe Dangote jade, bẹẹ ni ileese Bua atawọn ileeṣẹ simẹnti mi-in ti wa bayii. Sibẹ naa, ariwo pe ileeṣẹ Dangote lo wa ọrọ simẹnti mọya ni wọn n sọ, eyi ti ko si ri bẹẹ rara nitori pe onikaluku lo ni anfaani bayii lati ra simẹnti rẹ lọwọ ẹni to ba wu u lai si idiwọ kankan.
Bẹ o ba gbagbe, ẹgbẹ awọn gomina paapaa ti sọ fun ileeṣẹ to n mojuto ọrọ epo nilẹ wa, NNPCL, pe ki wọn maa ra epo nileeṣẹ ifọpo Dangote, dipo bi wọn ṣẹ n fowo ṣofo lati maa lọọ gbe epo wa lati ilẹ okeere, eyi ti wọn ni ko daa to fun ọrọ aje wa.