Ọwọ Amọtẹkun tẹ Adekunle o, ọgẹdẹ lọọ ji loko oloko

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ẹṣọ Amọtẹkun ipinlẹ Ọṣun ti mu ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn kan, Adekunle Omideyi, lori ẹsun ole jija.

Lẹyin ti Adekunle, ọmọ bibi ilu Ẹrinmọ-Ijeṣa, ji ọgẹdẹ ati koko (cocoa) atawọn nnkan oko mi-in ninu oko oloko ni ọwọ tẹ ẹ.

Gẹgẹ bi Alakooso ajọ naa, Ọnarebu Ọmọyẹle Adekunle, ṣe sọ, o ni ẹni to ni oko naa lo lọọ fiṣẹlẹ naa to Amọtẹkun leti pe ẹnikan ji nnkan ninu oko oun, to si sa lọ.

Bayii lawọn Amọtẹkun bẹrẹ iwadii, ko si pẹ rara tọwọ fi tẹ Adekunle ninu ile akọku kan to sapamọ si.

Nigba ti wọn n gba ọrọ lẹnu rẹ, o jẹwọ pe ki i ṣe igba akọkọ niyi toun yoo hu iru iwa bẹẹ, o ni ti oun ba ti ji nnkan loko oloko, oun ti ni awọn oniṣowo kan ti wọn maa n ra a lọwọ oun.

Ọmọyẹle ni awọn ti taari Adekunle lọ sọdọ ajọ sifu difẹnsi fun ẹkunrẹrẹ iwadii, pẹlu ileri pe ajọ naa ko ni i faaye gba ẹnikẹni ti ko ba ni i jẹ kawọn araalu fi alaafia ṣọdun. O waa ke si gbogbo awọn olugbe ipinlẹ Ọṣun lati jẹ oye ojulalakan fi n ṣọri, ti wọn ba ti kẹẹfin ẹnikẹni to n rin irin ifura, ki wọn tete fi to awọn agbofinro leti.

Leave a Reply