Faith Adebọla, Eko
Njẹ ọrọ ta a pe lowe ko ti n ni aro ninu bayii pẹlu ileeṣẹ ologun ilẹ wa ṣe ṣiṣọ loju eegun awuyewuye to n lọ lori bi wọn ṣe fẹsun kan wọn pe awọn ṣọja lo yinbọn pa awọn ọdọ to n ṣe iwọde tako SARS, wọn lawọn kọ lawọn yinbọn o, bo tilẹ jẹ pe ijọba ipinlẹ Eko lo pe awọn jade.
Ninu atẹjade kan to tẹ ALAROYE lọwọ, eyi ti ileeṣẹ ologun ilẹ wa, ẹka kọkanlelọgọrin kọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, adele fun Alukoro ileeṣẹ ologun ilẹ wa, Mejọ Ọlaniji Ọṣọba, sọ pe ko si ootọ ninu ahesọ ọrọ ati fọnran fidio to n ja ranyin pe awọn lawọn ṣina bolẹ fawọn ọdọ to n ṣe iwọde ni too-geeti Lẹkki lalẹ ọjọ Tusidee, ogunjọ oṣu kẹwaa yii.
O ni gbogbo eeyan gbọdọ ranti pe latigba tawọn ọdọ naa ti n ṣe iwọde, ileeṣẹ ologun ilẹ wa ko da si i, awọn ko si tako wọn tabi faramọ ohun ti wọn n ṣe.
O ni bi Gomina Sanwo-Olu kede ofin konilegbele oni-wakati mẹrinlelogun tan lọsan-an ọjọ naa lo ke si awọn ṣọja pe ki wọn ran oun lọwọ lati mu kawọn ọdọ naa so ewe agbejẹẹ mọwọ, ki wọn kuro loju titi.
O ni bawọn janduku kan ṣe ti n dana sun teṣan ọlọpaa, ti wọn ṣekupa awọn ọlọpaa kan, to si dabii pe apa ijọba ko fẹẹ ka kinni ọhun mọ, lo mu ki wọn kesi ileeṣẹ ologun lati fi ṣọja ranṣẹ, ki eto aabo ma baa wo lulẹ.
Mejọ Ọṣọba ni awọn ṣọja tawọn da sita tẹle ilana ati alakalẹ ti wọn gbọdọ pa mọ fun eto aabo abẹle, paapaa nigba ti ọrọ ba kan awọn araalu, yatọ si tawọn ọta, tori ni ko ṣe si ṣọja kan to yinbọn lu araalu kankan, ẹri to daju si wa lati fi gbe ọrọ yii lẹsẹ.
O lawọn to fẹẹ ba orukọ ileeṣẹ ologun ilẹ wa lo wa nidii ahesọ pe awọn ṣọja lo pa awọn ti wọn lo ku tabi fara pa lara awọn ọdọ naa, iru ẹsun bẹẹ, agbọgbọntinu ni kawọn eeyan gbọ ọ, tori ko si ootọ kọbọ ninu ẹ.
Ibeere tawọn eeyan n beere latigba ti atẹjade naa ti jade ni pe ta ni kawọn gbagbọ ninu gomina to sọ pe oun ko mọ nipa bawọn ṣọja ṣe jade lọọ doju ibọn kọ awọn to n ṣewọde, ati ileeṣẹ ologun to waa sọrọ fun igba akọkọ bayii pe ijọba ipinlẹ Eko lo ni kawọn jade, awọn ko si yinbọn fẹnikẹni.
Tẹ o ba gbagbe, abajade iṣẹlẹ naa lo fa idarudapọ to waye lọjọ Wẹsidee to tẹle e nigba tawọn ọdọ atawọn janduku to dara pọ mọ wọn bẹrẹ si i dana sun awọn dukia ijọba ati ti aladaani ti wọn si ṣakọlu rẹpẹtẹ sawọn teṣan ọlọpaa bii mẹtadinlọgbọn nipinlẹ Eko.
Ibeere tọpọ eeyan n beere latigba naa ni pe ta lo paṣẹ fawọn ṣọja ti wọn fi lọọ ṣe ohun ti wọn ni wọn ṣe ọhun.