Faith Adebọla, Eko
Bii aago mẹwaa owurọ ọjọ Aiku, Sannde yii, ni ipade nla kan waye niluu Eko, nibi ti gbogbo awọn gomina ilẹ Yoruba, awọn minisita ati awọn ọba gbogbo peju si, ti wọn si fẹnu ko pe ko saaye fun didibọn lori ọrọ eto aabo ilẹ Yoruba ati ti orileede yii mọ, afi ki atunto gidi de ba a bayii.
Gbọngan ipade nla to wa nile ijọba ipinlẹ Eko, ni Alausa, ni Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ti gba awọn to wa sipade naa lalejo.
Lara awọn gomina to pesẹ sipade naa ni Rotimi Akeredolu lati ipinlẹ Ondo, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde lati Ọyọ, Gboyega Oyetọla lati Ọṣun, Kayọde Fayẹmi lati Ekiti, ati Ọmọọba Dapọ Abiọdun, gomina ipinlẹ Ogun.
Ni isọri awọn lọbalọba, Ọọni ti Ile-Ifẹ, Ọba Ẹniitan Ogunwusi, Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi keji, Olubadan tilẹ Ibadan, Ọba Saliu Adetunji, Ọba tilu Eko, Ọba Riliwanu Akiolu, Ayangburẹn ti Ikorodu, Ọba Kabiru Ṣotobi, Olugbo tilẹ Ugbo, Ọba Ọlatẹru Ọlagbẹgi, Ọrangun ilu Ila, Ọba Adedokun Abọlarin, Ọlọwọ tilu Ọwọ, Ọba Ogunoye atawọn ori ade mi-in lo wa nibi apero ọhun.
Lara awọn minisita to peṣẹ sibẹ ni Alhaji Lai Mohammed, Ọgbẹni Babatunde Raji Fashola, Ọnarebu Ọlọrunnibẹ Mamora, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, Ọgbẹni Ọlamilekan Adegbitẹ, Ọgbẹni Niyi Adebayọ ati Ọgbẹni Sunday Dare.
Gomina ipinlẹ Ondo, to tun jẹ alaga awọn gomina ilẹ Yoruba, Rotimi Akeredolu, ati Ọọni Ifẹ, Ọba Ẹniitan Ogunwusi, lo buwọ lu atẹjade kan ti wọn fi sode lẹyin ipade naa.
Lara koko mẹtala to wa ninu atẹjade ọhun ni pe ki ijọba apapọ gbe abajade apero gbogbogboo to waye niluu Abuja lọdun 2014 lasiko iṣejọba Aarẹ Goodluck Jonathan sode, ki wọn ṣayẹwo awọn aba bii ẹgbẹta (600) tawọn aṣoju bii okoolenirinwo (420) naa ṣe lẹẹkan si i, ki wọn si ṣamulo awọn aba to yẹ nibẹ, paapaa lori ọrọ aabo ilu ati ilana pin-in-re, la-a-re eto inawo ati iṣakoso ẹya ati ẹkun gbogbo lorileede yii.
Wọn ni yanpọnyanrin to waye kọja yii lori iwọde ta ko SARS yii, ati awọn ajalu to tẹyin ẹ yọ, ti waa mu ko han pe eto aabo orileede yii lapapọ ko ṣee fọwọ dẹngẹrẹ mu mọ, ati pe agbegbe iwọ-Oorun Naijiria, iyẹn ilẹ Yoruba, nilo ọlọpaa pupọ si i ju bo ṣe wa yii lọ.
Atẹjade naa tun sọ pe bo tilẹ jẹ pe awọn fara mọ ibeere awọn to bẹrẹ iwọde ta ko SARS ko too di pe o di tawọn janduku, wọn ni iba daa ju ka sọ pe awọn igbesẹ pato tete waye lori iwọde ati ibeere awọn ọdọ naa, dipo ti ọrọ fi di ‘ọbẹ ge ọmọde lọwọ, ọmọ sọ ọbẹ nu’.
Wọn ni ki ijọba sọ ni pato awọn igbesẹ ti wọn ba fẹẹ gbe lati ṣatunṣe si awọn dukia ijọba atawọn nnkan iṣẹnbaye to ṣegbe lasiko rukerudo naa. Ṣaaju ni Gomina Sanwo-Olu ti sọ pe awọn ọkọ ti wọn dana sun ninu iṣẹlẹ naa lapaapọ le ni ẹẹdẹgbẹta, bẹẹ si ni awọn ile aladaani ati tijọba ti wọn fina si ju ọgọrun-un lọ, lai ka awọn dukia mi-in.
Koko mi-in ti wọn tun mẹnu ba ni bi awọn iroyin eke, igbekeyide ati irọ gbuu ṣe n fọn ka lasiko yii. Wọn ke si ijọba apapọ lati gbe eto kalẹ ti yoo kọ awọn eeyan lati ṣamulo awọn ikanni ati atẹ ayelujara lọna rere, sibẹ lai ṣediwọ fun ẹtọ ọmọniya awọn ọdọ ati araalu, tori aye imọ ẹrọ la wa yii. Wọn ni kijọba tete bẹrẹ si i ṣamulo ofin ilo intanẹẹti ti wọn ṣe lọdun 2015.
Wọn tun ta ijọba lolobo lati tete wa nnkan ṣe si ọrọ awọn olukọ fasiti gbogbo ti wọn ti daṣẹ silẹ, ki ajọ ASUU le kuro lẹnu iyanṣẹlodi wọn.
Aṣoju kan tijọba apapọ ran wa sipade naa, Ọjọgbọn Ibrahim Gambari, to jẹ Olori awọn oṣiṣẹ lọfiisi Aarẹ sọ lẹyin ipade naa pe apero yii maa jẹ ki ijọba to wa lode yii tun ero rẹ pa, ki wọn si san ṣokoto wọn giri lati wa awọn ọna to mọyan lori ti wọn yoo fi pese iṣẹ fawọn ọdọ, ki wọn le tubọ wulo lawujọ. O ni Aarẹ Buhari ti mọ nipa bi awọn nnkan to ṣofo niluu Eko lasiko rukerudo naa ṣe pọ to, oun yoo si tun jabọ ipade yii fun un, ijọba yoo si ṣe nnkan nipa rẹ.