Jide Kazeem
Gbogbo akitiyan ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọyọ lati ma faaye gba awọn to fẹẹ maa lo orukọ ikọ naa fi huwa ibi ti n so eso rere bayii pẹlu bi ọwọ ṣe tẹ awọn telọ kan niluu Ibadan, nibi ti wọn ti n ran ayederu aṣọ naa.
Ninu ọrọ ti alaga ẹṣọ agbofinro Amọtẹkun, Ọgagun Kunle Togun, sọ lori redio kan niluu Ibadan lo ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ awọn telọ aranṣọ kan ti wọn n ran ayederu aṣọ ẹṣọ agbofinro yii laduugbo Challenge, niluu Ibadan. O ni bi ọwọ ṣe tẹ wọn lawọn ti fa wọn le ọlọpaa lọwọ ni teṣan wọn to wa ni Yemetu, niluu Ibadan, fun iwadii to peye.
Baba yii ni agbegbe kan ti wọn n pe ni Lagelu, n’Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, ni wọn n ta awọn ayederu aṣọ ọhun si, ati pe awọn ẹṣọ Amọtẹkun ti wa ni gbogbo agbegbe naa bayii lati ṣawari awọn to ra a.
Togun sọ pe, “O ṣe pataki ki aṣiri awọn to n ra ayederu aṣọ yii tu, nitori ti a ko ba ri wọn mu, niṣe ni wọn yoo maa fi aṣọ Amọtẹkun ṣiṣẹ ibi, tawọn eeyan yoo si maa ro pe awọn eeyan wa lo n hu iwa ọdaran ọhun kiri, nigba ti wọn ba n ri aṣọ wa lọrun wọn.”