Okan, Sunday Igboho ti tu aṣiri nla nipa wahala to waye laarin oun atawọn ẹṣọ agbofinro to dena de e loju ọna Guru Maraji, niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, lasiko to n lọ si ilu Eko.
Igboho ni gbogbo ohun to wa ni ọkan awọn agbofinro to da oun duro ni pe wọn fẹẹ pa oun ni. Lasiko ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu Dokita Reubeni Abati lori eto redio kan lo ti sọrọ naa. O ni ọpọ awọn to ri i pe oun bọ aṣọ silẹ ko mọ ohun to fa a ti oun fi ṣe bẹẹ. O ni niṣe ni ọkan ninu awọn agbofinro naa lọ aṣọ mọ oun lọrun, to si fun un pinpin pẹlu erongba ati pa oun.
Igboho ni eyi lo mu ki oun kuku bọ aṣọ naa, ti awọn si bẹrẹ wahala gidi. O ni lẹyin ti oun bọsọ yii ni wọn bẹrẹ wahala buruku pẹlu oun, ti wọn si yinbọn soke.
‘‘Nnkan idojuti gbaa ni ọrọ naa jẹ fun mi. Ọmọluabi eeyan ni mi, ọmọ Yoruba si ni mi, mo si n ja fun ẹtọ Yoruba, nitori naa, ko si idi kankan fun wọn lati halẹ mọ mi.
‘‘Ọmọ orileede Naijiria ni mi, okoowo ni mo n ṣe, mo si n san owo-ori mi deede, bawo ni ma a ṣe waa maa lọ loju ọna ti awọn kan aa maa dena de mi lati pa mi.
‘‘Ilu ko fara rọ, awọn Fulani n ji awọn eeyan wa gbe, wọn n ba oko wọn jẹ, bẹẹ ni wọn n ba wa lobinrin sun, sibẹ, awọn agbofinro ko le koju wọn. Ijọba paapaa ko si ri nnkan kan ṣe si i, dipo ti wọn iba fi ṣe nnkan, niṣe ni wọn tun n kowo fun awọn ajinigbe.
‘‘ Ohun ti wọn ṣe lọjọ Ẹti yẹn, wọn fẹẹ pa mi ni.’’
Igboho ti waa fọrọ ranṣẹ sijọba apapọ atileeṣẹ agbofinro pe ki wọn yee fẹtẹ silẹ maa pa lapalapa kiri, o ni ki wọn yọ orukọ oun kuro lara awọn eeyan ti wọn maa maa rẹburu ẹ kiri, o ni Shehu Gumi ati Shekau, olori awọn Boko Haraamu, ni ki wọn kọkọ lọọ mu na.
Sunday ni niṣe nijọba n fi ohun to yẹ ki wọn ṣe silẹ, ti wọn ko ṣe e, pẹlu bi eto aabo ṣe n fojoojumọ buru si i, ṣugbọn to jẹ ọtọ lawọn ti wọn fẹẹ fi pampẹ ofin gbe.
O ni ni toun, oun o bẹru awọn ọlọpaa rara, tori oun o jale tabi ṣe aburu kan, awọn janduku agbebọn to yẹ kawọn ọlọpaa mu wa nibẹ, wọn o mu wọn. Bẹẹ ni wọn ko sọrọ nipa Sheu Gumi, ọkunrin to n lọọ dunaa-dura pẹlu awọn janduku to n ji awọn eeyan gbe. O ni kijọba yaa lọọ jawọ l’apọn ti o yọ, ki wọn lọọ da omi ila ka’na.
Yatọ si Sunday Igboho, ọgọọrọ eeyan lo ti bẹnu atẹ lu bawọn agbofinro kan lati ẹka ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ati ọlọpaa ṣe lọọ rẹbuu mọto ọkunrin naa lọsan-an ọjọ Ẹti ọhun, ti wọn si fẹẹ fi tipatipa mu un sakolo wọn.
Ibi ipade pataki kan ti wọn fẹẹ ṣe lọdọ olori ẹgbẹ Afẹnifẹre nni, Alagba Ayọ Adebanjọ, ni wọn n lọ kawọn ọlọpaa, awọn otẹlẹmuyẹ atawọn ẹṣọ agbofinro mi-in bii ogoji too lọọ dena de Oloye Sunday Adeyẹmọ, nitosi ibi ti ileejọsin Guru Maharajhi wa, mimu ti wọn fẹẹ fipa mu ọkunrin naa lọ lo di ariwo, debii pe niṣe ni Sunday bọ aṣọ ẹwu to wọ, to yan gende ọmọkunrin gidi.
Ariwo yii lawọn aladuugbo atawọn ọdọ agbegbe naa gbọ ti wọn fi sare de ibi iṣẹlẹ ọhun, ti wọn si ba awọn agbofinro naa fa a pe awọn o ni i jẹ ki wọn mu Sunday Igboho lọ.
Nigba tọrọ naa fẹẹ di yanpọnyanrin, tawọn ọdọ naa si n leri lati gbinaya ija lawọn agbofinro naa fẹyin rin, ti wọn ko si mu Sunday Igboho mọ, niṣe ni wọn n wo o titi to fi ko sinu ọkọ, to si gbọna Eko lọ ni tirẹ.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Ẹti, Furaidee, ọse to kọja ni ariwo deede gba ilu pe awọn agbofinro fẹẹ fipa gbe ajijagbara naa.
Minisita fun ileeṣẹ ofurufu nilẹ wa tẹlẹ, Oloye Femi Fani-Kayọde lo sare fi ọrọ naa lede, to ṣalaye pe ‘‘Mo ṣẹṣẹ ba arakunrin mi, Sunday Igboho, sọrọ tan laipẹ yii ni, o si sọ fun mi pe pẹlu ijakadi ni awọn ṣọja, ọlọpaa, awọn ọtẹlẹmuyẹ fi fẹẹ mu oun loju ọna marosẹ Ibadan si Eko lasiko ti oun n lọ siluu Eko lati lọọ ri Baba Ayọ Adebanjọ.’’
Fani-Kayọde bu ẹnu atẹ lu igbesẹ naa, o ni iwa buruku ti o si lewu ni awọn eeyan naa hu.
Bo tilẹ jẹ pe a ko mọ hulẹhulẹ ohun ti ipade ti wọn lọọ ṣe naa da le lori, ṣugbọn gbogbo awọn to mọ bo ṣe n lọ ni wọn n sọ pe lori wahala awọn darandaran ni, a gbọ pe lẹyin ipade naa, Sunday Igboho tun lọ sile Aarẹ Ọna kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams, ti wọn si jọ tilẹkun mọri sọrọ.
Ẹgbẹ Afẹnifẹre naa ti sọrọ lori iṣẹlẹ yii. Ọgbẹni Yinka Odumakin sọ pe nnkan ti ko bojumu gbaa ni bi wọn ṣe fẹẹ mu Sunday Igboho ni papa-n-koko, bii ọdaran. O ni ijangbọn gidi nijọba n fa lẹsẹ ti wọn ba gun le ṣiṣe bẹẹ.
Ṣọṣọ ni atẹ ayelujara ṣi n ho fun bawọn eeyan lẹlẹgbẹjẹgbẹ ati ẹnikọọkan ṣe n bẹnu atẹ lu ohun tawọn agbofinro ṣe naa, wọn ni ko si idi kan lati fi pampẹ ofin gbe ẹni to n ja fun ẹtọ awọn eeyan rẹ.
Amọ ṣa o, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti sẹ kanlẹ pe ki i ṣe pe awọn fẹẹ fi pampẹ ofin gbe Oloye Adeyẹmọ, wọn lawọn kan beere ọrọ lọwọ rẹ lasan ni.