Ọwọ tẹ Fẹmi atawọn ẹgbẹ ẹ to maa n ja foonu gba ni pati l’Akurẹ

Faith Adebọla

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo lo ṣafihan awọn mẹrẹẹrin tẹ ẹ n wo ninu fọto yii, wọn ni iṣẹ gbewiri ni wọn mu lọkun-unkundun ni tiwọn, foonu onifoonu ni wọn n ji kaakiri ibi ayẹyẹ l’Akurẹ.

Orukọ awọn afurasi ọdaran naa ni Fẹmi Ojo, ẹni ọgbọn ọdun, Abiọdun Adewale, ẹni ọdun marundinlaaadọta, Kọlawọle Ọlanrewaju, ẹni ọdun marundinlaaadọta, ati Kọla Aiwọle, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn.

Opin ọsẹ to kọja yii lọwọ ba wọn nibi gbọngan ayẹyẹ International Event and Cultural Centre, tawọn eeyan maa n pe ni Dome, niluu Akurẹ. Ibẹ lawọn jagunlabi yii sọ di ọfiisi ole jija wọn, latari bo ṣe jẹ pe loorekoore lawọn eeyan n lo gbọngan naa fun oriṣiiriṣii ayẹyẹ, bi pati ba si ti n lọ lọwọ, awọn naa n ba iṣẹ jiji foonu lọ niyẹn.

Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN) to jẹ ka ri iroyin  yii gbọ sọ pe ikọ ọlọpaa Operation Scorpion lo mu awọn afurasi ọdaran wọnyi nigba ti wọn n dari rele wọn loju ọna Ileṣa si Akurẹ. Nigba ti wọn mu wọn, wọn sọ fawọn ọlọpaa pe ibi ọtọọtọ lawọn n gbe, ẹnikan loun n gbe ni Ọyọ, ẹlomi-in ni ipinlẹ Ọṣun nile oun wa, ṣugbọn ti pati ba ti wa ni Dome lawọn maa n waa jale.

Foonu olowo nla oriṣii mẹfa ni wọn ba lapo ọkan ninu wọn, Adewale, nigba ti wọn si beere ibi to ti ri wọn, o loun ri gbogbo ẹ he nilẹ ni.

Fẹmi Ojo ni wọn loun jẹwọ ni tiẹ pe niṣe loun ji awọn foonu ti wọn ba lọwọ oun, o ni tawọn eeyan ba ti n jo ni pati loun maa n yọ foonu naa lapo wọn. Wọn tun bi i pe bawo lo ṣe n ṣe e tawọn onifoonu ko fi ni i mọ, o sọ pe kikọ ni mimọ, oun ti pafẹẹti (perfect) ole jija ni.

Wọn ni ọkan ninu wọn tun jẹwọ pe awọn si yọ foonu lasiko tawọn kan n ṣayẹyẹ ibura saa ẹlẹẹkeji Gomina Akeredolu lopin ọsẹ naa. Ṣa, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ondo, Ọgbẹni Tee-Leo, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O lawọn ti taari wọn sọdọ awọn agbofinro to n ṣiṣẹ iwadii, ati pe awọn afurasi naa maa balẹ sile-ẹjọ laipẹ.

Leave a Reply