Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Nitori awọn ẹsun iwa jagidijagan ati dida omi alaafia ilu ru ti wọn fi kan Igbakeji abẹnugan ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, Ọnarebu Dare Kadiri, ile naa ti gbe igbimọ ti yoo ri si awọn ẹsun ti wọn fi kan an dide.
Mẹrindinlọgbọn ni awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin Ogun, ogun ninu wọn lo ti fọwọ si i pe ki wọn yọ Dare Kadiri nipo to wa.
Eyi lo fa a ti Akọwe ile naa, Ọgbẹni Deji Adeyẹmọ, fi jẹ ko ye igbimọ lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii ti wọn jokoo lọfiisi wọn l’Oke-Mosan, pe oun ti fi iwe ẹsun wọn ranṣẹ si Kadiri, o si ti da esi pada, igbimọ ti yoo si jokoo lori ẹsun naa ati esi rẹ ti wa nikalẹ.
Awọn igbimọ ti yoo ṣiṣẹ lori ọrọ yii gẹgẹ bi Ọlakunle Oluọmọ, olori ile naa ṣe ka a ni: Olori ọmọ ẹgbẹ to pọ ju lọ;Yusuf Sheriff (Alaga)AbdulBashir Ọladunjoye, Bọlanle Ajayi, Adeyẹmi Ademuyiwa, Modupẹ Mujọta ati Temitọpẹ Hokon to jẹ akọwe wọn.
Ṣe lọsẹ to kọja yii ni awọn ọlọpaa lati Kọmandi l’Abẹokuta, mu Dare Kadiri ti i ṣe Igbakeji ile-igbimọ aṣofin Ogun, wọn lo ko danjuku lẹyin lọọ ba ile Ọgbẹni Tokunbọ Talabi jẹ, iyẹn Akọwe ijọba fun Gomina Dapọ Abiọdun.
Wọn fi kun un pe awọn eeyan mẹta mi-in lọkunrin yii tun kọ lu, to ba dukia wọn jẹ nitori awọn nnkan eelo iforukọsilẹ ẹgbẹ APC to n wa kiri.
Kadiri ko ti i ba ile naa jokoo ipade latigba naa, iwadii ṣi n lọ lori rẹ latọdọ awọn ọlọpaa. Bẹẹ ni ile-igbimọ paapaa n ṣiṣẹ tiwọn lati mọ ootọ to wa nidii iṣẹlẹ naa, ati pe boya yiyọ ni yoo gbẹyin ọkunrin yii, boya wọn yoo si fi i silẹ ko maa ba iṣẹ rẹ lọ ni.