Faith Adebọla
Igbakeji olori ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, Ọnarebu Oludare Kadiri, ti wọn yọ nipo l’Ọjọbọ, Tọsidee, ti sọ pe awada nla lawọn ti wọn yọ oun n ṣe, o ni iyọnipo naa ko bofin mu, ko lẹsẹ nilẹ, ko si le duro niwaju ofin.
Ọnarebu Oludare sọrọ yii kete tawọn aṣofin naa fi ibo yọ ọ nipo lasiko ijokoo wọn to waye ni gbọngan apero ile-aṣofin naa l’Ọjọbọ, Tọsidee.
Oludare to n ṣoju awọn eeyan ẹkun idibo Ariwa Ijẹbu keji nile aṣofin naa, sọ pe “Mo ṣẹṣẹ n gbọ iroyin pe wọn lawọn aṣofin kan yẹ aga mọ mi nidii latari abọ iwadii ti igbimọ alabẹ-ṣekele gbe kalẹ ni. To ba jẹ loootọ ni, igbesẹ yii ta ko ofin ilẹ wa, ko si bofin mu ni gbogbo ọna.
“Mo ti kan si lọọya mi, a si ti n fikun lukun lati le mọ ọna to daa ju ta a maa fi yanju ọrọ yii, ati igbesẹ to yẹ lati gbe. Iwa ikọja aaye lawọn aṣofin naa hu, apara nla ni wọn si n da.
“Mo parọwa sẹyin ololufẹ mi, ẹyin eeyan ẹkun idibo ti mo ti wa, ati ẹyin ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni ẹkun idibo Ariwa Ijẹbu, lati ṣe suuru, a maa yanju gbogbo ohun to n run nilẹ bii iso buruku yii.
“Ipokipo ki mo wa lasiko yii tabi ti mo ba ara mi lọjọ iwaju, mo ṣi maa rọ mọ awọn ilana iṣẹ aṣofin ati ti iṣejọba demokiresi to le mu ijọba rere wa.”
Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja yii lawọn aṣofin mejilelogun nile aṣofin ipinlẹ naa fọwọ si iwe ẹsun aṣemaṣe kan ti wọn kọ ta ko Ọnarebu Oludare, wọn lo huwa abuku nla, ko si yẹ ko wa nipo igbakeji olori awọn aṣofin ile naa.
Latari eyi, Olori awọn aṣofin naa, lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, gbe igbimọ oluwadii kan dide lati yiri awọn ẹsun ti wọn fi kan ọkunrin yii, boya awọn ẹsun naa lẹsẹ nilẹ, to ba si jẹ bẹẹ, ki wọn dabaa ijiya to tọ. Ọnarebu Yusuf Sheriff lalaga igbimọ ọhun.
Awọn igbimọ naa ti ṣewadii, wọn si ti jabọ fun ile, abajade iwadii wọn ọhun lawọn aṣofin mọkandinlogun ninu awọn mẹrindinlọgbọn naa lawọn gun le ti wọn fi dibo yọ Ọnarebu Oludare Kadiri nipo.