Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun ti yan Ọnarebu Akeem Balogun Agbọlade gẹgẹ bii Igbakeji abẹnugan, lẹyin ti wọn yọ Oludare Kadiri to wa nipo naa kuro lọsẹ to kọja.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu kẹta yii, ni awọn aṣofin yan Ọnarebu Akeem Balogun, nibi ijokoo wọn to waye l’Oke-Mosan, l’Abẹokuta.
Ọnarebu Balogun ti wọn yan yii lo n ṣoju agbegbe Ogun Waterside, nileegbimọ yii, oun naa ni alaga to n ri si ijọba ibilẹ ati oye jijẹ nile igbimọ aṣofin Ogun. Ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni.
Ibo ni wọn fi yan Balogun sipo yii. Akọwe ile, Ọgbẹni Deji Adeyẹmọ, lo ṣe kokaari idibo naa lẹyin ti Ọnarebu Solomon Ọṣhọ to n ṣoju Ariwa Rẹmọ darukọ Balogun bii ẹni tile fẹ, ti Abayọmi Fasuwa to n ṣoju Ariwa Ijẹbu si kin in lẹyin.
Adeyẹmọ ṣalaye pe ile yọ Oludare Kadiri to wa nipo naa kuro lẹyin ti ọmọ ẹgbẹ mọkandinlogun ti fọwọ si iyọkuro rẹ, eyi lo si fa a ti ipo naa fi ṣofo, to si di dandan lati fi ẹlomi-in rọpo rẹ.
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin iyansipo rẹ, Balogun dupẹ lọwọ awọn ọmọ ile-igbimọ to yan an sipo yii, bẹẹ lo fi da Abẹnugan Ọlakunle Oluọmọ loju pe oun yoo jẹ oloootọ si i ni gbogbo ọna, ati si gbogbo ile pẹlu.
O loun yoo maa ba Abẹnugan jiroro lori ohun gbogbo ti yoo mu ilọsiwaju ba ipinlẹ Ogun ni.
Ẹ oo ranti pe ọsẹ to kọja yii ni wọn yọ Oludare Kadiri to wa nipo igbakeji abẹnugan naa kuro nipo, lẹyin ẹsun aṣemaṣe gbogbo ti wọn fi kan an.