Faith Adebọla
Yoruba bọ, wọn ni bonile o ba fura, ole aa ko o lẹru lọ. Owe yii lo wọ ikede pataki kan ti ẹgbẹ ajafẹtọọ ilẹ Yoruba, Apapọ Oodua Kọya (AOKOYA) ṣe lasiko yii ti wọn fi n pe awọn gomina ilẹ Yoruba sakiyesi pe ki wọn ma kawọ gbera maa woran, tori olobo ta awọn pe awọn janduku agbebọn ti ṣetan lati maa ji awọn ọmọleewe gbe nilẹ Yoruba, paapaa nipinlẹ Ogun, Ọyọ ati Ondo bayii.
Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ naa fi lede fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, ti ẹda rẹ tẹ ALAROYE lọwọ, nibẹ lẹgbẹ naa lawọn ti kọwe si ọkọọkan awọn gomina ipinlẹ mẹtẹẹta tọrọ kan lopin ọsẹ to kọja yii pe afi ki wọn tete gbe awọn igbesẹ kanmọkanmọ bayii, wọn lawọn agbebọn naa fẹẹ maa wọ awọn ileewe alakọọbẹrẹ ati girama, wọn fẹẹ maa ji awọn akẹkọọ gbe sa lọ.
Atẹjade naa, ti Ọgbẹni Ahmed Akorede buwọ lu lorukọ ẹgbẹ ọhun, ka lapakan pe:
“Awọn janduku agbebọn ti sami si awọn ibi ti wọn fẹẹ ṣakọlu si nipinlẹ Ondo, Ọyọ ati Ogun, wọn si ti n kọ ibuba kaakiri awọn igbo to yii agbegbe naa ka, wọn n ko nnkan ija sibẹ. Lara awọn agbẹbọn kan ti wọn wa ni ipinlẹ Niger, Zamfara ati Kaduna ni wọn, ibẹ ni wọn ti ṣeto wọn wa.
“A gbọ finrinfinrin pẹlu ọgbọn-inu gidi ni, olobo to ta wa ki i ṣe ṣereṣere rara. O lawọn ọna kan ta a maa n gba gbọrọ nipa ohun tawọn agbẹbọn naa n sọ lede wọn (ede Fulfulde). Ibẹ la ti gbọ pe wọn fẹẹ ji awọn ọmọleewe wa ko rẹpẹtẹ ni.
“Baa ṣe n sọ yii, wọn ti de agbegbe Yewa, nipinlẹ Ogun, ati agbegbe Oke-Ogun, nipinlẹ Ọyọ, wọn si ti wa ni Idanre, nipinlẹ Ondo.”
Ẹgbẹ AOKOYA tun sọ pe awọn kọlọransi ẹda kan ti wa ninu awọn to n ṣejọba Naijiria tawọn oṣiṣẹ ọba kan n kowo gidi fun, bẹẹ lawọn orileede Aarin-Gbungbun Ila-Oorun aye meji kan wa ti wọn fẹẹ sọ orileede wa di ojuko awọn agbebọn atawọn apanilaya (terrorists).
Wọn ni kawọn wọnyi, titi kan ti Eko, Kogi, Ọṣun, Kwara ati Ekiti lo ọgbọn-inu, ki wọn si lo ilana ‘ki o too gbe mi wọnlẹ, mo ti ba abẹ ẹ yọ’ fawọn ọta wọnyi.
Ẹgbẹ naa waa dabaa igbesẹ mẹta kan ti wọn lo ṣe pataki gidi fawọn gomina yii lati gbe. Lara igbesẹ naa ni pe ki wọn tete ṣawari awọn ileewe to ṣee ṣe kawọn janduku naa fẹẹ tete kọ lu, ki wọn si ṣeto aabo fun wọn ni yajoyajo.
Wọn tun dabaa pe kawọn ilu ati abule kọọkan bẹrẹ si i kọ ile-oluṣọ to maa ga to ẹsẹ bata mẹẹẹdogun soke, to si maa ni awọn ohun eelo teeyan fi n wo ọna jinjin lọsan-an loru, ati pe ki wọn ṣatunto ikọ Amọtẹkun, ki wọn pese idanilẹkọọ nipa ọrọ aabo, ki wọn si gba oṣiṣẹ pupọ si i.