Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Bisọla Awodele lẹ n wo yii, obinrin ẹni ọdun mẹtalelogoji (43) to bimọ marun-un fun ọkọ ẹ, Peter Philips, ṣugbọn to mọ-ọn-mọ da omi gbigbona si i lara lọjọ kẹjọ, oṣu kẹta yii, nile wọn ni Sango Ọta. O ni nitori ọkọ oun ko wulo ni, ko si mọ ju ko maa mu ọti kiri lọ.
DSP Abimbọla Oyeyẹmi lo fi iṣẹlẹ yii to AKEDE AGBAYE leti laaarọ ọjọ Aiku, Sannde ọsẹ yii. Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun naa ṣalaye pe Peter Philips, ọkọ Bisọla, lo gbe ara bibo lọ si teṣan ọlọpaa lọjọ naa, to si ni iyawo oun lo da omi gbigbona soun lara.
Nigba ti awọn ọlọpaa lọọ mu iyawo yii nile, o ni loootọ loun da omi gbigbona sọkọ oun lara, ohun to fa a ni pe o maa n mu ọti yo ni, alẹ lo si maa n wọle to ba ti yo binaku tan.
O ni ọkọ oun ki i gbọ bukaata lori awọn ọmọ toun bi fun un, oun naa loun n da gbọ gbogbo ẹ.
Bisọla sọ fawọn ọlọpaa pe lọjọ toun da omi gbigbona si i lara yii, niṣe lo tun mu ọti yo wale bii iṣe rẹ, oun si n sọrọ si i pẹlu bo ṣe mu ọti yo naa.
O ni bi Philip ṣe bẹrẹ si i bu oun, to tun n sọrọ sawọn obi oun niyẹn.
Eyi lobinrin naa sọ pe o bi oun ninu toun fi gbe omi gbigbona, toun da a si i lara.
Iwadii wọn lori obinrin yii fidi ẹ mulẹ pe o bimọ kan ni nnkan bii oṣu mẹjọ sẹyin, ṣugbọn niṣe lo pa ọmọ naa funra ẹ, to si da a sin, lai jẹ ki ẹnikẹni mọ. Wọn ni nitori bi nnkan ṣe ri fun un naa ni.
Ikọ atọpinpin to ri aṣiri yii, de ibi to sin ọmọ naa si i, wọn si ti hu iyooku ara ọmọde naa jade gẹgẹ bi Alukoro ṣe sọ.
Ọkọ to da omi gbigbona lu naa lẹ n wo ti wọn we ni bandeeji lọsibitu yii, wọn si ti gbe Bisọla funra ẹ lọ sẹka itọpinpin iwa ọdaran.