Ijọba ni kawọn ọga ati olukọ awọn ileewe to n fa wahala hijaabu pada sẹnu iṣẹ kiakia

Stephen Ajagbe, Ilorin

 

Lẹyin rogbodiyan to bẹ silẹ laarin awọn ẹlẹsin Kristẹni atawọn Musulumi lori ọrọ lilo hijaabu lawọn ileewe tawọn ọmọlẹyin Kristi da silẹ, eyi to mu ki awọn ileewe mẹwaa kan di titi pa, ijọba ipinlẹ Kwara ti paṣẹ fun awọn ọga ati olukọ awọn ileewe naa lati pada sẹnu iṣẹ wọn bẹrẹ lati ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹta, ọdun yii.

Alaga ajọ to n mojuto eto ẹkọ nipinlẹ Kwara, Teaching Service Commission, TESCOM, Mallam Bello Tahueed Abubakar, lo paṣẹ naa l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ninu atẹjade kan ti akọwe iroyin rẹ, Amọgbọnjaye Peter, fi sọwọ sawọn oniroyin.

Abubakar ni o ṣe pataki fun awọn olukọ naa lati pada sẹnu iṣẹ ki wọn le ṣeto imurasilẹ fun idanwo aṣekagba fawọn akẹkọọ to n mura WAEC.

O ṣekilọ pe olukọ tabi oṣiṣẹ to ba kọ lati wa sẹnu iṣẹ lọla (Furaidee) yoo da ara rẹ lẹbi.

Bakan naa lo ṣekilọ fawọn tọrọ kan lati ma fa wahala kankan nitori pe ipade alaafia pẹlu ijọba ṣi n tẹsiwaju.

 

Leave a Reply