Florence Babaṣọla
Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti paṣẹ pe ki alakooso iṣẹ awọn ikọ alaabo Amọtẹkun, Oloye Amitolu Shittu, fara han niwaju igbimọ oluwadii kan ti wọn gbe kalẹ lori ọrọ ti wọn lo kọ sori ẹrọ ayelujara laipẹ yii.
Ninu ọrọ ti Amitolu kọ lo ti fẹsun kan olori awọn oṣiṣẹ lọọfiisi gomina, Dokita Charles Akinọla, ati Oludamọran pataki fun gomina lori eto aabo, Iyaafin Abiọdun Ige, pe wọn ko tọ si ipo ti wọn di mu lọwọlọwọ ninu ijọba.
Amitolu sọ pe afomọ lasan lasan ni Akinọla, bi idibo ba si n waye nigba igba nipinlẹ Ọṣun, ko le jawe olubori nibudo idibo rẹ, ka ma tiẹ ti i sọ wọọdu rẹ, sibẹ, ṣe lo n fungun mọ awọn to fara jiya fun ẹgbẹ APC.
Ni ti Abiọdun Ige, ẹni to ti figba kan jẹ kọmiṣanna funleeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Amitolu ṣapejuwe obinrin naa gẹgẹ bii igi wọrọkọ, to kan n fi ẹsin boju lasan, ṣugbọn to jẹ olojukokoro, amọtara-ẹni-nikan ati afọrọkẹlẹ ba tẹnikeji jẹ ni.
Latari awuyewuye ti ọrọ yii ti da silẹ ni Kọmiṣanna feto iroyin ati ilanilọyẹ, Funkẹ Ẹgbẹmọde, ṣe kede pe Gomina Oyetọla ti gbe igbimọ oluwadii, eleyii ti Akọwe ijọba, Ọmọọba Wọle Oyebamiji, yoo jẹ alaga fun, kalẹ.
Ẹgbẹmọde ṣalaye pe Amitolu yoo fara han niwaju igbimọ naa lati sọ ohun to ri lọbẹ to fi waro ọwọ.