Stephen Ajagbe, Ilorin
Awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun Aiye ati Ẹiyẹ mẹrindinlogun lọwọ ọlọpaa tẹ lagbegbe Oko-Olowo, niluu Ilọrin, pẹlu awọn ohun ija oloro.
Mẹrin ninu wọn lo jẹ obinrin, ti mejila si jẹ ọkunrin.
Ọga ọlọpaa Kwara, Muhammed Lawal Bagega, lo ṣafihan wọn l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii. O ni pẹlu iranlọwọ araalu lọwọ fi tẹ awọn afurasi naa.
Bagega ni ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n gbogun ti ijinigbe ati ẹgbẹ okunkun pẹlu ifọwọsowọpọ fijilante, ni wọn jọ ya bo awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa, ti wọn fi ko si pampẹ.
O ni awọn ohun ija oloro bii ibọn, ada, aake, oogun, ọpọlọpọ igbo, lawọn ba lọwọ wọn.
Ọkunrin naa fi kun un pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo tẹsiwaju lati maa fọwọsowọpọ pẹlu awọn ẹṣọ alaabo yooku lati gbogun ti iwa ọdaran nipinlẹ Kwara.
Ọga ọlọpaa naa tun ni awọn ti ṣawari ibọn agbelẹrọ mẹfa nibi tawọn ọdaran kan fara pamọ si nijọba ibilẹ Moro, nipinlẹ Kwara.
O ni awọn ti n gbiyanju lati ri awọn to ni ibọn naa mu ki wọn le foju bale-ẹjọ. O rọ araalu lati ran ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ nipa tita wọn lolobo lasiko ti wọn ba kẹẹfin awọn ti irin ẹsẹ wọn ko mọ lagbegbe wọn.