Azeez Agboọla lorukọ ọkunrin ti ẹ n wo yii, ẹni aadọta ọdun (50 years) ni. Iṣẹ lọọya lo n ṣe jẹun lọjọ to ti pẹ, bo tilẹ jẹ pe ayederu ni. Ṣugbọn nigba tọwọ ba a lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹta, 2021, o loun kẹkọọ nipa ofin, bo tilẹ jẹ pe oun ko paasi, oun ko yege nileewe rara.
Aṣiri Azeez to tu yii ko deede tu, ẹnu iṣẹ lọọya naa lo wa ti ọwọ fi tẹ ẹ. Kootu Majisireeti agba to wa ni Agbara, nipinlẹ Ogun, lo ti n gbẹjọ ro fẹnikan lọwọ lọjọ naa, ṣugbọn bo ṣe n gbe ọrọ kalẹ ati iṣesi rẹ ni kootu fu Adajọ agba, B. I Ilo, lara.
Eyi lo mu adajọ naa pe awọn ọlọpaa, wọn si waa mu Azeez Agboọla lati fọrọ wa a lẹnu wo daadaa ki wọn le mọ boya lọọya gidi ni loootọ.
DPO teṣan Agbara, SP Dahiru Saleh, lo fọrọ wa ọkunrin yii lẹnu wo, afurasi ọdaran naa si jẹwọ fun un pe loootọ, oun lọ si yunifasiti, oun kẹkọọ nibẹ lati di lọọya, o ni ṣugbọn oun ko yege idanwo toun yoo fi di amofin nileewe awọn lọọya,( Law school), ileewe naa ko si foun niwee-ẹri aṣeyege gẹgẹ bii amofin.
O ni ṣugbọn ohun tohun yoo jẹ lo jẹ koun kuku bẹrẹ iṣẹ agbẹjọrọ lai jẹ pe oun yege lati ṣe bẹẹ.
Lati pe ara ẹni loun ti a ko jẹ lodi sofin, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi si lawọn yoo gbe ayederu lọọya yii lọ si kootu laipẹ, gẹgẹ bi aṣẹ CP Edward Ajogun