Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Awọn eeyan mẹta kan, Jibril Afọlabi, Alhaji Amusat Taofeek ati Balikis Mohammed ti awọn ajinigbe kan ji gbe loju ọna Ṣiun/Ajura, Ogere Rẹmọ, nipinlẹ Ogun, lọjọ kin-in-ni, oṣu kẹrin yii, ti gba itusilẹ bayii. Awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun to gba wọn silẹ sọ pe wọn ko sanwo kankan ki wọn too gba ominira.
Atẹjade ti Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, fi sita lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keji, oṣu kẹrin yii, lo ti ṣalaye pe Ilọrin lawọn eeyan mẹta naa ti n bọ, Owode-Ẹgbado ni wọn si n lọ ti awọn kan fi dabuu mọto wọn ni nnkan bii aago mẹta oru, ti wọn ja wọn bọ silẹ ninu ọkọ, wọn si gbe wọn wọgbo lọ.
Kia lawọn ọlọpaa oriṣiiriṣii wọgbo naa lọ bi Oyeyẹmi ṣe wi, nitori bẹẹ ni CP Edward Ajogun ṣe paṣẹ. Wọn yigbo ọhun po, wọn si da lilọ bibọ ọkọ duro lagbegbe naa.
Pẹlu iranlọwọ awọn ọdẹ ibilẹ, fijilante atawọn ẹṣọ So-Safe, awọn ajinigbe naa fi awọn ti wọn ji gbe silẹ, wọn sa lọ raurau. Alukoro sọ pe nnkan bii aago mẹfa aarọ lawọn ri awọn ti wọn ji gbe naa.
Bayii lawọn ti wọn ji gbe naa ṣe gba itusilẹ lai sanwo kankan, awọn ọlọpaa si sin wọn de ibi ti wọn n lọ l’Owode-Ẹgbado.