Mẹta lara awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Alora ko sọwọ ọlọpaa niluu Ileefẹ

Florence Babaṣọla

Lẹyin wahala ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ba ara wọn fa a niluu Oṣogbo, ti i ṣe olu-ilu ipinlẹ Ọṣun, ni nnkan bii oṣu kan sẹyin, ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ti tẹ mẹta lara awọn ti ẹgbẹ Buccaneer ti gbogbo eeyan mọ si Alora, niluu Ileefẹ.

Ninu wahala ija agba to waye laaarin awọn ẹgbẹ okunkun Ẹyẹ, Aiye ati Alora, niluu Oṣogbo, ni wọn ti pa Akinwale Rotimi lagbegbe Arikalamu, Ṣogo Owonikoko, lagbegbe Ọbatẹ, ati Daniel, lagbegbe Kọlawọle.

Latigba naa, gẹgẹ bi Kọmiṣanna ọlọpaa l’Ọṣun, Wale Ọlọkọde, ṣe sọ fawọn oniroyin, o ni awọn ọlọpaa ti n dọdẹ awọn ọmọ ẹgbẹ yii kaakiri ilu Oṣogbo, Ile-Ifẹ ati Ikire.

Ọgbọnjọ, oṣu kẹta, ọdun yii, ni ọwọ ba Akintunde Moses, to jẹ ọmọ ọdun mọkanlelogun, Adedayọ Ọlamilekan to jẹ ọmọ ọdun mejilelogun ati Ayọmipọ Oluyẹmi to jẹ ọmọ ogun ọdun.

Ibọn pelebe kan, English Revolver Pistol, ni wọn ri lakata wọn, gẹgẹ bi Ọlọkọde ṣe wi, o ni awọn mẹtẹẹta ni wọn sọ pe akẹkọọ lawọn niluu Ileefẹ, ti wọn si jẹwọ pe loootọ lawọn wa ninu Alora.

Ọlọkọde waa kilọ fun awọn obi lati ba awọn ọmọ wọn sọrọ daadaa, pe ki wọn jawọ ninu iwa jagidijagan ati iwa ẹgbẹ okunkun ṣiṣe, ai jẹ bẹẹ, awọn naa yoo kawọ pọnyin sọ idi ti wọn fi n ti awọn ọmọ wọn lẹyin ninu iwa ibi.

Leave a Reply