Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ileeṣẹ C-WAY ti wọn n ṣe nnkan mimu loriṣiiriṣii niluu Ọta, nipinlẹ Ogun ni Mutiu Ọlaonipẹkun, ẹni ọdun mejilelọgbọn ti n ṣiṣẹ dẹrẹba. Ṣugbọn lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹta, ọdun 2021 yii, o dari ọja ti wọn ni ko gbe lọ fun kọsitọma sọdọ onibaranda ti wọn jọ dowo-pọ, iyẹn Kayọde Afọlabi, o si ta ọja miliọnu mẹrin aabọ naira (4.5m)fun un ni miliọnu meji aabọ o le diẹ (2,572,000)
Gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, ṣe ṣalaye iṣẹlẹ naa, o ni bi wọn ṣe ko ọja kun inu tirela ti Mutiu n wa, ni wọn ro pe yoo ṣe gbe e lọ fun onibaara ti ileeṣẹ ran an si n’Isọlọ, l’Ekoo. Ṣugbọn lati ọjọ kẹẹẹdogun oṣu kẹta naa ni wọn ko ti gburoo rẹ, bẹẹ ni wọn ko ri mọto rẹ to n wa pẹlu.
Eyi lo mu awọn alaṣẹ ileeṣẹ naa lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Onipaanu, l’Ọta, wọn si bẹrẹ si i ṣe iwadii lori ohun to le ṣẹlẹ si dẹrẹba naa ati ọja ti wọn ko fun un.
Lẹyin ọsẹ diẹ, awọn ọlọpaa ri tirela Mutiu nibi kan lagbegbe Ewupe, l’Ọta, ṣugbọn ko si ọja kankan ninu ẹ mọ.
Iwadii naa lo jẹ ki wọn mọ pe niṣe ni dẹrẹba yii ko ọja inu mọto naa sinu ọkọ mi-in, to si lọọ ta a fun Kayọde Afọlabi lowo to le diẹ ni milọnu meji.
Awọn mejeeji lọwọ awọn ọlọpaa pada tẹ, Mutiu to taja naa si ṣalaye pe oun ra ọkọ bọọsi LT kan ninu owo naa. Miliọnu kan din lẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan naira (900,000) lo ni oun ra a, oun si fi owo to ku ta tẹtẹ ti wọn n pe ni ‘Bet Naija’
Ni ti Kayọde to ra ọja ole, o loun ti tun awọn ọja naa ta fun Alaaji kan torukọ ẹ n jẹ Adamu Kano, iyẹn si ti sa lọ bayii.
Ọga ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Edward Ajogun, ti ni ki wọn tete pari iwadii to ba ku lori awọn eeyan yii, ki wọn le foju bale-ẹjọ kia.