Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Inu ibẹru lawọn eeyan Ikẹrẹ-Ekiti wa di akoko yii latari akọlu tawọn ọmọ ẹgbẹ kan ṣe niluu naa, eyi to fa iku eeyan mẹfa laarin ọjọ Abamẹta, Satide, si ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.
Ko sẹni to mọ nnkan to da wahala silẹ gan-an, ṣugbọn ikọ ẹgbẹ okunkun meji la gbọ pe wọn gbe omi ija kana lẹyin ti wọn pa ẹnikan ti wọn pe ni Ojuale, ẹni to wa si ilu naa lati Port Harcourt fun ayẹyẹ igbeyawo ọrẹ ẹ.
Ojuale ti wọn pe ni ọmọ ẹgbẹ okunkun lawọn ikọ mi-in yinbọn pa loru mọjumọ lagbegbe gbọngan ilu Ikẹrẹ, lagbegbe Odo Ọja. Iṣẹlẹ naa ni wọn lo da wahala nla silẹ pẹlu bi awọn ẹgbẹ ẹ ṣe da ibọn bolẹ ti wọn si pa eeyan mẹfa.
Ọrọ naa da ipaya silẹ, awọn araalu si ke sijọba ki wọn gba wọn lọwọ awọn ọdaran ọhun, eyi to fa bi awọn ọlọpaa ṣe ya bo awọn agbegbe ti wahala ti n ṣẹlẹ.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Alukoro ọlọpaa Ekiti, ASP Sunday Abutu, sọ pe loootọ ni wahala waye lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, si aarọ Sannde, awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun lo si fa a. O ni awọn mẹfa to padanu ẹmi wọn ti wa ni mọṣuari.
Abutu ni, ‘Awọn igun ẹgbẹ okunkun meji kan lo fẹẹ fi agba han ara wọn niluu Ikẹrẹ-Ekiti, ṣugbọn a ti lọ sibẹ lati da alaafia pada. Lọwọlọwọ, akojọpọ awọn ọlọpaa, ṣọja, Amọtẹkun ati Sifu Difẹnsi lo n kaakiri ilu naa bayii.
‘‘Lori ọrọ yii, awọn mẹwaa lọwọ ti tẹ, iwadii si n lọ lọwọ lati mọ igbesẹ ti wọn gbe ninu iṣẹlẹ naa. Ni kete ta a ba pari iwadii wa ni wọn yoo foju bale-ẹjọ.’’