Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Awọn bii mẹrinlelọgbọn lawọn ọlọpaa ti mu lori rogbodiyan to waye niluu Ikẹrẹ-Ekiti lopin ọsẹ to kọja, nibi ti akọlu tawọn ọmọ ẹgbẹ kan ṣe ti fa iku eeyan mẹfa laarin ọjọ Abamẹta, Satide, si ọjọ Aiku, Sannde.
Ko sẹni to mọ nnkan to da wahala silẹ gan-an, ṣugbọn ikọ ẹgbẹ okunkun meji la gbọ pe wọn gbe omi ija kana lẹyin ti wọn pa ẹnikan ti wọn n pe ni Ojualẹ, ẹni to wa si ilu naa lati Port Harcourt fun ayẹyẹ igbeyawo ọrẹ ẹ.
Ojualẹ ti wọn pe ni ọmọ ẹgbẹ okukun lawọn ikọ mi-in yinbọn pa loru mọjumọ lagbegbe gbọngan ilu Ikẹrẹ, nitosi Odo Ọja. Iṣẹlẹ naa ni wọn lo da wahala nla silẹ pẹlu bi awọn akẹgbẹ ẹ ṣe da ibọn bolẹ, ti wọn si pa eeyan mẹfa tawọn eeyan pe ni ọmọ ẹgbẹ okunkun.
Ọrọ naa da ipaya silẹ, awọn araalu si ke sijọba ki wọn gba wọn lọwọ awọn ọdaran ọhun, eyi to fa bi awọn ọlọpaa ṣe ya bo awọn agbegbe ti wahala ti n ṣẹlẹ.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Alukoro ọlọpaa Ekiti, ASP Sunday Abutu, sọ pe loootọ ni wahala waye lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, si aarọ Sannde, awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun lo si fa a. O ni awọn mẹfa to padanu ẹmi wọn ti wa ni mọṣuari.
Abutu ni, ‘‘Awọn igun ẹgbẹ okunkun meji kan lo fẹẹ fi agba han ara wọn niluu Ikẹrẹ-Ekiti, ṣugbọn a ti lọ sibẹ lati da alaafia pada. Lọwọlọwọ, akojọpọ awọn ọlọpaa, ṣọja, Amọtẹkun ati Sifu Difẹnsi lo n kaakiri ilu naa bayii.
‘‘Lori ọrọ yii, awọn mẹwaa lọwọ ti tẹ, iwadii si n lọ lọwọ lati mọ igbesẹ ti wọn gbe ninu iṣẹlẹ naa. Ni kete ta a ba pari iwadii wa ni wọn yoo foju bale-ẹjọ.’’
Nigba ti yoo fi di ọjọ Mọnde, awọn bii mẹrinlelọgbọn lọwọ tun tẹ lori iṣẹlẹ naa, ALAROYE si gbọ pe awọn marundinlaaadọta ni wọn ti wa lakolo ọlọpaa bayii.
Bakan naa lawọn kan sọ pe awọn bii mejila lo ti gbẹmi-in mi lori iṣẹlẹ ọhun lapapọ, bo tilẹ jẹ pe a ko le fidi eleyii mulẹ lasiko ta a pari akojọpọ iroyin yii.