Faith Adebọla, Eko
Ijọba ipinlẹ Eko ti paṣẹ pe ki wọn tilẹkun gbogbo ibudo ti wọn ti n fawọn eeyan labẹrẹ ajẹsara COVID-19 kaakiri ipinlẹ naa lasiko yii na, wọn lawọn ti so eto gbigba abẹrẹ ajẹsara naa rọ.
Kọmiṣanna feto ilera, Ọjọgbọn Akin Abayọmi, lo kede eyi ninu atẹjade kan to fi lede l’Ọjọbọ, Tọsidee yii.
O ni ipinnu lati dawọ duro lori fifun awọn araalu labẹrẹ ajẹsara ọhun ki i ṣe eyi ti ipinlẹ Eko da nikan ṣe, aṣẹ lati ọdọ ajọ ijọba apapọ lori eto ilera alabọọde (National Primary Healthcare Development Agency, NPHCDA) ni, lati Abuja ni wọn ti ni kawọn ṣi dawọ duro lori kinni ọhun na.
Akin Abayọmi ni nipele-ipele ni eto abẹrẹ ajẹsara naa, ipele akọkọ leyi tawọn n ṣe lọ yii, aropọ awọn to gba abẹrẹ naa nipinlẹ Eko si jẹ ẹgbẹrun lọna ọtalerugba o din mẹta, ọtalelẹẹẹdẹgbẹrin o din mẹrin (257,756) eeyan.
O ni lati ogunjọ, oṣu kẹta, tawọn ti gba abẹrẹ ajẹsara tijọba apapọ pin fun ipinlẹ Eko lawọn ti bẹrẹ si i gun abẹrẹ naa fawọn oṣiṣẹ ati araalu, ojoojumọ si lawọn n ṣiṣẹ titi di ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja yii, tawọn dawọ rẹ duro.
“Ipinlẹ Eko ti gun kọja idaji aropọ abẹrẹ ajẹsara tijọba fi ṣọwọ si wa, a gun abẹrẹ naa fawọn oṣiṣẹ eleto ilera, awọn oṣiṣẹ eleto aabo, awọn to wa lawọn ẹnubode wa gbogbo, awọn oṣiṣẹ lẹka eto idajọ, ileepo, awọn oniroyin atawọn tiṣa. A tun fun gbogbo awọn tọjọ ori wọn ba ti to aadọrin tabi ju bẹẹ lọ, ti wọn ba lawọn fẹẹ gba a. Eko nikan la ti gun abẹrẹ to ju igba lọ.”
Kọmiṣanna naa ni ile iko-nnkan-pamọ nijọba ipinlẹ Eko lawọn maa ko awọn abẹrẹ to ku ti wọn o ti i gun pamọ si, tori eto gbigba apa keji abẹrẹ naa maa too bẹrẹ.
Abayọmi rọ gbogbo awọn to ti gba abẹrẹ ajẹsara apa kin-in-ni yii, lati tọju kaadi pelebe ti wọn fun wọn, ki wọn si fi ọjọ ti wọn ba kọ sinu rẹ sọkan, tori ipele keji abẹrẹ ajẹsara naa maa too bẹrẹ laipẹ.