Stephen Ajagbe, Ilorin
Ọga ọlọpaa ni Kwara, Mohammed Lawal Bagega, ti kede pe awọn doola oniṣowo pataki nni, Alhaji Alaga Ọlayẹmi, lahaamọ awọn ajinigbe to gbe e lọ lọna oko rẹ lọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹrin, ọdun yii, niluu Oke-Onigbin, nijọba ibilẹ Isin, nipinlẹ Kwara.
Atẹjade latọwọ Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Ajayi Ọkasanmi, nirọlẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtalelogun, ṣalaye pe awọn ri baba ẹni ọdun mọkandinlaaadọrin naa gba pada.
O ni lẹyin tawọn ya wọ igbo gẹgẹ bii aṣẹ ọga ọlọpaa lawọn ajinigbe naa yọnda ọkunrin yii, ti wọn si fẹsẹ fẹ ẹ nigba ti wọn ri i pe ọwọ ti fẹẹ ba wọn.
Ọkasanmi ni gbogbo agbegbe Oke-Onigbin, Ilọffa, Ekiti, titi de Eruku lawọn tu kaakiri lasiko tawọn n wa ọkunrin naa.
O ṣalaye siwaju pe abule kan to n jẹ Oyogbo, lawọn ajinigbe naa fi baale ile naa si ko too di pe wọn sa lọ.
Wọn ni ọkunrin naa wa nilewosan, nibi ti wọn ti n ṣe ayẹwo fun un. Awọn agbofinro ni akitiyan ṣi n lọ lati ri i pe ọwọ tẹ awọn ajinigbe naa.
Ọga ọlọpaa fi da araalu loju pe aabo to peye wa fun ẹmi ati dukia wọn, ṣugbọn ki wọn ran ileeṣẹ awọn lọwọ nipa fifọwọsowọpọ pẹlu wọn lati gbogun ti iwa ọdaran nipinlẹ Kwara.