Faith Adebọla
Agba ọjẹ oloṣelu ilu Eko nni, to tun jẹ aṣaaju apapọ fẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ti sọ pe lai ka awọn ipenija to n koju orile-ede yii si, oun mọ pe awọn araalu ṣi nifẹẹ si ẹgbẹ oṣelu APC, ati pe ko ru’ju rara, ẹgbẹ naa maa wa lori aleefa kọja ọdun 2023, o ni ẹgbẹ APC lo maa bori eto idibo gbogbogboo to n bọ.
Tinubu sọrọ yii lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, nigba to n dahun ibeere awọn akọroyin nileeṣẹ Aarẹ lẹyin ipade toun ati Aarẹ Muhammadu Buhari tilẹkun mọri ṣe lori ipenija eto aabo to n ba ilẹ wa finra lọwọ yii. Oloye Bisi Akande, gomina ipinlẹ Ọṣun tele ati alaga apapọ fẹgbẹ oṣelu APC nigba kan wa nipade naa pẹlu.
Bọla Tinubu ni ohun to da oun loju t’adaa ni pe Aarẹ Muhammadu Buhari ko ni i lo wakati kan tayọ asiko to yẹ ko gbejọba silẹ, o ni Buhari ṣee gbekẹle pe ko ni i gbiyanju lati sun asiko to yẹ ki iṣakoso rẹ kogba sile siwaju tayọ ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun 2023, tori ọkunrin naa mọ ofin o si maa n bọwọ fun ofin ilẹ wa.
O ni “Ohun ti mo mọ ni pe awọn eeyan ṣi nifẹẹ si ẹgbẹ oṣelu wa (APC), ko si ruju rara pe ẹgbẹ naa maa maa tẹsiwaju niṣo lati ṣiṣẹ fun igba ọtun orileede Naijiria, o maa ṣiṣẹ kọja ọdun 2023.
“A o le maa ki ọrọ oṣelu ati abamoda awọn eeyan bọ gbogbo nnkan, ba a ṣe fẹẹ mu orileede yii tẹsiwaju lo gbọdọ jẹ wa logun. A ni ijọba ta a maa fa le ara wa lọwọ, Buhari o si ni i fi wakati kan kọja asiko to yẹ ko gbejọba silẹ, o maa tẹle ofin ilẹ wa.
“Loootọ, ko si orileede ti ko ni ibi ti bata ti n ta wọn lẹsẹ, gbogbo wọn ni wọn ni ipenija ti wọn n la kọja, ṣugbọn bawo la ṣe fẹẹ ṣalaye ẹ fawọn eeyan, bawo la ṣe maa mu ko rọrun faraalu lati fara da a, awọn ibi to yẹ ka wo niyẹn lori ba a ṣe fẹẹ paarọ olori orileede yii laipẹ.
“Afi ki gbogbo wa fori kori lati din awọn agbebọn yii ku, ka si jẹ ki iṣọkan gbilẹ, ki Naijiria le sunwọn si i, tori igbaye-gbadun awọn araalu ṣe pataki gidi.”
Tinubu kadii ọrọ rẹ pe Aarẹ Buhari nifẹẹ awọn gbogbo ọmọ Naijiria pata, ọrọ wọn wa lookan aya ẹ gidi, ko si dun mọ ọn bi wọn ṣe n foju wina iṣoro lasiko yii rara.