Ihooho ni pupọ ninu wọn jade, paapaa awọn ti wọn jẹ agbalagba ninu wọn. Awọn obinrin agbegbe Zango Kataf, ni Kaduna, ni wọn jade lati fi ẹhonu han, nitori ipakupa ti awọn Fulani onimaaluu n pa wọn ni ipinlẹ naa, to si jọ pe apa ijọba apapọ, ati ijọba ipinlẹ naa, ko ka a rara. Fun bii ọsẹ mẹta nilẹ yii ni iku naa ti tun bẹrẹ lakọtun, ti eeyan ko si le ka iye awọn ti wọn ti pa danu. Lọsẹ to kọja yii nikan, o le ni aadọrin eeyan tawọn apaayan Fulani naa pa, lati abule si abule ni wọn si n pa wọn, ti wọn n ba dukia wọn jẹ, ti wọn si n ji awọn ohun-ini wọn mi-in ko lọ. Ohun to jẹ kawọn obinrin yii jade ni bi awọn Fulani onimaaluu naa ṣe ya bo awọn abule kan ni alẹ Mọnde to kọja, ti wọn si bẹrẹ si i pa awọn eeyan ibẹ bii pe ẹran ni wọn n pa, nigba ti yoo fi di pe wọn ṣetan laarin wakati kan ti wọn debẹ, eeyan mejidinlogoji ni wọn ti pa.
Ni Fadan Karshi ni wọn ti kọkọ pa wọn, awọn mọkanlelogun ni wọn si pa nibẹ. Lẹyin naa ni wọn rin lọ si Nandu, ti wọn si pa eeyan mẹtadinlogun. Ọwọ kan naa ni wọn fi n pa wọn, ilana kan naa si ni wọn n tọ. Bii ogun, bii ọgbọn awọn Fulani wọnyi yoo gbe ara wọn sori ọkada, wọn yoo si ya lu abule ti wọn ba fẹẹ ko ogun ja naa. Ibọn ti wọn n pe ni AK47 yoo wa lọwọ ẹnikọọkan wọn, bẹẹ ni wọn yoo si ni awọn ohun ija oloro mi-in bii daga ati ida oloju meji lọwọ wọn. Wọn ti kọkọ lọọ kọ lu wọn ni abule Kukum Daji ni o ku ọtunla ti wọn yoo waa pa awọn eeyan ti wọn ṣẹṣẹ pa yii. Ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja lọhun-un ni, awọn kan ni wọn n ṣeyawo nibẹ, ti wọn si n jo, ti wọn n yọ, awọn ko si mọ pe awọn Fulani onimaaluu apaayan yii ti gbọ nipa inawo ti wọn yoo ṣe, ayẹyẹ ti wọra nigba ti wọn ja lu wọn lojiji.
Abule Kukum Daji yii daru lẹsẹkẹsẹ ni, nitori loju ẹsẹ lawọn apaayan yii ti mu awọn eeyan mẹẹẹdogun balẹ, wọn pa wọn pata nipakupa, bẹẹ ni wọn si ṣe awọn ti wọn le ni bii ọgbọn leṣe, ti wọn ṣa wọn ladaa yanna yanna, ti awọn mi-in si fara gba ọta ibọn. Yatọ si pe wọn da igbeyawo ru, abule naa paapaa daru, nitori ọpọlọpọ awọn eeyan ibẹ ni wọn sa jade, wọn si ni awọn ko ni i de agbegbe naa mọ lae. Ṣugbọn o fẹrẹ jẹ pe ko si ibi kan tawọn Fulani apaayan yii da si ni gbogbo apa Guusu ipinlẹ Kaduna yii, nibi to jẹ kidaa awọn Kristẹni lo n gbebẹ. Ni Zango Kataf, ọkan lara awọn ilu to wa nibẹ, ni ọjọ kejidinlogun, ọsu yii, ni abule Gora Gan, eeyan mẹsan-an ni wọn pa danu nibẹ bii ẹni n ṣere. Aago meje alẹ ni wọn debẹ, ti wọn si da ibọn bolẹ, ti wọn yinbọn yii pa awọn eeyan mẹsan-an nibi ti wọn ti n sa lọ.
Awọn ohun to jẹ kawọn obinrin ibẹ jade nihooho ree, ti wọn ni awọn yoo foju kan ọba, awọn yoo si foju kan ijoye, awọn yoo jẹ ki wọn mọ ohun to n ṣe awọn gan-an. Awọn obinrin yii ni bi ijọba ba sọ pe awọn ko gbọ, tabi pe awọn ko mọ pe ẹni kan n ku, tabi pe awọn Fulani fẹẹ run awọn tawọn ni gbogbo adugbo naa, awọn ti jade bayii lati jẹ ki ijọba ri awọn, nibi to si ka awọn lara de lawọn ṣe rin ihooho wọlu, ki ijọba le mọ pe ọrọ naa ki i ṣe ere rara. Ohun to waa yaayan lẹnu, to ba awọn ara orilẹ-ede agbaye lẹru ju ni pe lọjọ keji ti awọn obinrin yii rin nihooho yii, awọn Fulani onimaalu yii tun jẹwọ fun wọn pe awọn ko ti i ṣetan pẹlu wọn, awọn ṣẹṣẹ bẹrẹ ni. Eeeyan mẹwaa ni wọn pa, eyi to si buru ju ni ti pasito ọdọmọde kan to dajọ igbeyawo rẹ sọna, ṣugbọn ti awọn afẹmiṣofo yii ko jẹ ko duro ṣe e.
Pasitọ ijọ awọn ECWA ni, Shama Kuyet Ishaya lorukọ rẹ. Asiko ti awọn apaayan naa de abule ***Zipakak ni wọn mu un balẹ, nibi ti oun naa ti n gbiyanju lati gba awọn kan la, to n sọ ọna ti wọn yoo gba sa lọ fun wọn. Wọn pa a pẹlu awọn mẹsan-an mi-in, lọjọ keji ti awọn obinrin yii jade nihooho ni, eyi to fi han pe awọn araabi naa ti mura ogun. O jọ pe ko si horo kan ti wọn ko si ni gbogbo awọn ijọba ibilẹ to wa ni Guusu Kaduna yii. Awọn Kristẹni nikan lo wa nibẹ, o si pẹ ti wọn ti jọ n gbe pẹlu awọn Fulani mi-in. Ṣugbọn lati igba ti ijọba yii ti wa nita, iyẹn ijọba Gomina Nasir El Rufai, ni awọn Fulani ti wọn n paayan ti waa le si i gan-an. Lojoojumọ ni. Loootọ ni gomina yii n pariwo pe awọn n gbiyanju lati ri i pe ẹmi awọn eeyan ko ṣofo mọ, ṣugbọn awọn eeyan ko gbagbọ, nitori ijọba ko ri ninu awọn Fulani apaayan yii mu rara.
Ko si tabi-ṣugbọn ninu ẹ, awọn Fulani lo n pa wọn, nitori ni gbogbo ibi ti wọn ba ti lọọ kọ lu wọn, ede Fulani yii ni wọn yoo maa sọ, ti wọn yoo si maa wi leti awọn oniluu naa pe awọn yoo le wọn kuro ni gbogbo agbegbe naa patapata. Ohun to n fa ija nibẹ ko ju pe awọn Fulani yii fẹran lati maa lọọ ji ire oko awọn agbegbe to wa lapa agbegbe yii, bẹẹ ni wọn fẹ lati maa fi maaluu wọn jẹ oko oloko, nigba ti ọrọ naa si wọ wọn lara tan, wọn fẹẹ maa gba ilu oniluu mọ awọn oniluu naa lọwọ, ki wọn si maa gbebẹ funra wọn. Ohun to jẹ ki ija naa le lati bii ọdun meloo sẹyin ree, iha ti Gomina El-Rufai si kọ si ọrọ naa, koda, titi doni, ki i ṣe iha to dara loju awọn eeyan, nitori ohun ti oun n tẹnu mọ ni pe ija ẹlẹyamẹya ni, pe awọn eeyan yii fẹẹ le awọn Fulani ọdọ wọn lọ ni. Ṣugbọn o han si gbogbo aye bayii pe awọn Fulani yii ni apaayan, nitori ko si ninu awọn araalu naa to n pa Fulani, awọn Fulani yii lo n pa awọn eeyan kiri.
Loootọ ni Aarẹ Muhammadu Buhari ni oun da si ọrọ iku to n pa wọn ni Kaduna yii, ṣugbọn ọna to gba da si i ko tẹ Ẹgbẹ awọn Onigbagbọ orile-ede yii lọrun rara, ibinu lọrọ naa mu jade lati ọdọ awọn CAN, ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi. Garba Shehu lo fọwọ si iwe kan to ni Buhari lo fi iṣẹ bẹẹ ran oun, ninu ẹ ni Aarẹ si ti sọ pe awọn n gbiyanju tawọn o, awọn ti ko ṣọja ati awọn ọmọ ogun mi-in si Guusu Kaduna, ṣugbọn o jọ pe ati awọn Fulani ati awọn ọmọ oniluu ni wọn jọ n para wọn, ati pe janduku lawọn to n pa wọn, janduku lawọn ti wọn n pa. Ọrọ naa bi CAN ninu, wọn ni o han pe Buhari ko mọ ohun to n lọ ni ayika rẹ. Wọn ni latigba ti ọrọ yii ti bẹrẹ, o di lemọọmu meloo ti awọn janduku yii pa, ṣebi awọn pasitọ ni wọn n lọọ ka mọ ṣọọṣi wọn ti wọn si n pa wọn. Ṣe janduku lawọn pasitọ ti wọn n pa yii ni.
Ṣugbọn ki i ṣe CAN lo n binu, awọn ọmọ agbegbe naa, paapaa awọn to wa nilẹ okeere ninu wọn, ti dide sọrọ yii. Oriṣiiriṣii ẹgbẹ lo ti dide, lara awọn ipinnu wọn si ni pe bi ijọba Naijiria ko ba le gba awọọ lọwọ awọn Fulani to n pa awọn eeyan awọn yii, awọn yoo dide lati gbeja ara awọn, awọn yoo si wa iranlọwọ lọ sita. Wọn ni nigba ti ibọn ba de ọwọ awọn eeyaan awọn naa, ti awọn ba jọ koju ara awọn, ọrọ naa ko ni i mọ ni agbegbe Guusu Kaduna nikan, yoo kari gbogbo ipinlẹ naa, ati awọn ipinlẹ to ba yi awọn ka ni. Wọ ni ẹni to ba mọ oju ijọba yii ko kilọ fun wọn. Bi ko si ni ohun ti ajanaku jẹ tẹlẹ ikun, ko ni i ṣe ikun tandi si ọlọdẹ, ọpọ awọn orillẹ-ede agbaye, paapaa lawọn orilẹ-ede to jẹ tawọn Kristẹni ni wọn koriira ohun to n ṣẹlẹ ni Kaduna yii, ti wọn si mura lati ṣeranwọ fawọn eeyan Kaduna yii ti wọn ba dide ogun laduugbo wọn. Bi ọrọ yii ko ṣe ni i dogun, ti ko ni i di wahala nla, ọwọ ijọba Naijiria lo wa o.