Florence Babaṣọla
Lasiko ti a n kọroyin yii, eeyan mẹjọ lo ti ku nibi ijamba ọkọ tirela nla kan to pada sẹyin lori biriiji kan ti wọn n pe ni November 27, loju-ọna Oṣogbo si Ọfatẹdo, niluu Oṣogbo.
Aago kan kọja ogun iṣẹju nidaaji oni ni ọkọ tirela Volvo alawọ buluu naa to ni nọmba KMC 35 ZJ n gun ori biriiji pẹlu ọpọlọpọ kẹẹgi epo pupa atawọn eeyan mọkanlelọgọta ti wọn jokoo lori rẹ.
Ṣugbọn lojiji ni mọto naa bẹrẹ si i pada sẹyin nigba ti ko lagbara lati gun oke naa mọ, to si sọ ijanu rẹ nu. Bayii ni kẹẹgi epo pupa bẹrẹ si i ja bọ, ti awọn eeyan ori rẹ naa si bẹrẹ si i bọ lulẹ.
Bi tirela naa ṣe n pada sẹyin ni kẹẹgi epo n ja le awọn ero ori rẹ lori nilẹẹlẹ, loju ẹsẹ lawọn mẹjọ si ti gbẹmi-in mi.
Alukoro ajọ ẹṣọ ojupopo l’Ọṣun, Agnes Ogungbemi, sọ pe eeyan mẹrindinlogoji lo fara pa, nigba ti eeyan mẹtadinlogun ko fara pa.
Ogungbemi ṣalaye pe Seeiki Hausa nipinlẹ Ọṣun ti waa ko oku awọn to ku ọhun lati le lọọ sin wọn, nigba ti awọn to fara pa wa nileewosan Aṣubiaro ati LAUTECH, fun itọju.
O fi kun pe bi ilẹ ṣe ṣu, ti ilẹ si n yọ loru yẹn, lo fa ijamba naa, ati pe awọn ti wọ ọkọ tirela naa kuro loju ọna.
Iwadii di han pe ojiji niṣẹlẹ naa ba pupọ ninu awọn to wa lori ọkọ naa, koda, ọpọlọpọ ninu wọn ni wọn ti sun lasiko to ṣẹlẹ, to si jẹ pe oju oorun lọpọ wọn gba de oju iku.