Makinde pese ileeyagbẹ alagbeeka, o ni ẹni ba tun ṣegbọnsẹ sẹgbẹẹ titi yoo jiya

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lati le fopin si bi awọn ara ipinlẹ Ọyọ ṣe maa n ṣegbọnsẹ si aarin igboro kaakiri, paapaa ju lọ nigboro Ibadan ti idọti pọ si ju lọ, ijọba ipinlẹ naa ti pese awọn ileegbọnsẹ alagbeeka si awọn aaye pataki ni ipinlẹ naa.

Kọmiṣanna feto amojuto ọrọ ayika nipinlẹ Ọyọ, Dokita Abdullateef Oyeleke, lo kede igbesẹ naa faye gbọ nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ n’Ibadan.

O ni lara ọna ti awọn eeyan n gba fi ẹgbin ba igboro jẹ ni bi awọn arinrin-ajo ṣe maa n ṣegbọnsẹ sibikibi ti wọn ba ti le ri nnkan fi boju, tabi ribi fara pamọ si, ati pe idi ree to fi jẹ pe awọn aaye ti ọpọ eeyan maa n gba kọja daadaa ni wọn yoo kọkọ ṣe awọn iṣi akọkọ ileegbọnse wọnyi si.

Ọkunrin dokita naa sọ pe lara awọn akanṣe iṣẹ ti Gomina Makinde fẹẹ fi ṣami ọdun keji rẹ lori aleefa nipese awọn ileegbọnsẹ wọnyi jẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Aadọta (50) ileegbọnsẹ alagbeeka lo ti wa nilẹ bayii. Aarin ọja, garaaji atawọn aaye to ṣe pataki kaakiri igboro lawọn ilu nla nla la maa gbe wọn si.

“Pẹlu akanṣe iṣẹ yii, o ti deewọ fun ẹnikẹni lati maa ṣegbọnsẹ si aarin igboro bayii. Awọn aṣoju ijọba yoo si maa lọ kaakiri lati maa mu ẹnikẹni to ba tun ṣegbọnsẹ si ilẹẹlẹ fun ijiya to lagbara bayii.”

O fi kun un pe laipẹ si asiko yii nijọba yoo gba awọn ọdọ kan ṣiṣẹ. Ohun ti wọn yoo si maa ṣe ni lati maa ṣamulo awọn igbọnsẹ ti awọn eeyan ba ṣe sinu ileegbọnse igbalode wọnyi fún ipese awọn nnkan mi-in ti yoo tun wulo fawọn eeyan láwùjọ.

 

Leave a Reply