Ni Ọjọbọ, Alamisi, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kọkanla, 1964, wọn ju Mark Ogbod sẹwọn ọdun kan niluu Owerri, nilẹ Ibo lọhun-un ti wọn n pe ni Eastern Region nigba naa. Ẹwọn oṣelu lọkunrin naa lọọ ṣe. Idi si ni pe wọn ti n wa a tipẹ, oun nikan lọmọ ile-igbimọ aṣofin ilẹ Ibo yii to jẹ ọmọ ẹgbẹ NPC, ẹgbẹ awọn Sardauna lati ilẹ Hausa. Bawo ni ẹgbẹ awọn Hausa yoo ṣe rọwọ mu nilẹ Ibo; bawo ni ọmọ Ibo kan ko ṣe ni i ri ẹgbẹ mi-in ṣe ju ẹgbẹ wọn nilẹ Hausa lọ. Nigba toun naa yoo si ko si wọn lọwọ, wọn ba kaadi idibo ojilelẹgbẹta-din-mẹfa (634) lọwọ rẹ, n lawọn yẹn ba sọ pe kaadi to fẹẹ fi ṣojooro nibi ibo to n bọ ni. Mark Ogbodo ni ki i ṣe bẹẹ, awọn kan ti ko mọwe ni wọn ko kaadi naa waa foun pe ki oun fọna han wọn nidii ẹ. Adajọ loun o gba, o lo da oun loju pe o fẹẹ lo kaadi naa fun ojooro ni. Ni wọn ba la a mẹwọn.
Oun nikan ko lo n lọ sẹwọn bẹẹ, bi awọn ẹgbẹ oṣelu mẹtẹẹta ti wọn lagbara ju nigba naa ṣe n sọ awọn alatako wọn sẹwọn ati atimọle niyẹn. Ẹgbẹ NPC lo lagbara nilẹ Hausa, Dẹmọ lo lagbara nilẹ Yoruba, NCNC lo si jẹ apaṣẹ nilẹ Ibo. Gbogbo wọn ni wọn ko si fẹ alatako kan ni agbegbe wọn, eyi lo ṣe jẹ bi ibo ti n sun mọle ni wọn n rọ awọn eeyan da satimọle, tabi sẹwọn, lai woju wọn. Ni ọjọ kẹrin ti wọn sọ Ogbodo sẹwọn nilẹ Ibo, awọn mejidinlọgbọn aṣaaju UPGA ni awọn ọlọpaa Western Region mu ni ilu Ọta ati Atan. Ẹṣẹ kan naa ni wọn ṣẹ nibi mejeeji, wọn ni wọn waa wo iwe iforukọsilẹ lati da wahala silẹ nibẹ ni. Bẹẹ ohun ti awọn yẹn n wi ni pe ọpọlọpọ orukọ to wa ninu awọn iwe naa ki i ṣe orukọ awọn eeyan ti wọn n gbe adugbo tawọn, Ọlọrun lo mọ ibi ti wọn ti ko wọn wa, bẹẹ orukọ tawọn gan-an ko si ninu iwe.
Ni ọgbọnjọ, oṣu kọkanla, 1964 yii, kan naa, wọn ju awọn aṣaaju ẹgbẹ UPGA mẹta sẹwọn ni Abẹokuta. Ẹni akọkọ ninu wọn ni Fọlọrunṣọ Ọyalọwọ. Ọmọ ẹgbẹ AG ni, o si ti figba kan jẹ aṣaaju ile-igbimọ aṣofin Western Region. Oun atawọn mẹji mi-in ni wọn ju sẹwọn, wọn ni wọn n ṣepade lai gbaṣẹ. Awọn tọhun lawọn ko ṣepade, ọrọ lasan lawọn n sọ; awọn ọlọpaa to mu wọn ni aaye ko si fun iru adurosọrọ bẹẹ lasiko naa, nitori wọn ko le bura pe ki i ṣe ọrọ oṣelu lawọn n sọ. Lọjọ yii kan naa ni wọn wọ awọn mẹta mi-in lọ sile-ẹjọ ni Ebute-Mẹta, l’Ekoo, ohun ti wọn tori ẹ wọ wọn bẹẹ ni pe wọn ni wọn n rin nitosi ile Alaaji Tijani, ẹni to fẹẹ du ipo lasiko ibo naa lorukọ ẹgbẹ Dẹmọ. Bi nnkan ti ri lasiko yii ree, ko si ọmọ ẹgbẹ Action Group, NCNC, tabi UPGA to gbọdọ ta felefele nilẹ Yoruba: bi ọwọ Dẹmọ ba to o, ẹwọn lo n lọ.
Ohun ti wọn si ṣe n ṣe bayii ni pe ẹru n ba olori ẹgbẹ naa gan-an, iyẹn Oloye Ladoke Akintọla. Bi ẹgbẹ Dẹmọ ba ja kulẹ, ti ẹgbẹ alajọṣepọ awọn ati NPC ti wọn jọ n jẹ NNA ko ba wọle, to ba jẹ UPGA to jẹ ẹgbẹ alajọṣepọ AG ati NCNC lo wọle ibo awọn aṣofin naa, ti ijọba si di tiwọn, omi gbẹ leyin ẹja fun Akintọla niyi, ohun buruku yoo si maa ja lu ara wọn fun un ni. Awọn UPGA tilẹ ti n leri: KIngsley Mbadiwe, ọkan pataki ninu awọn aṣaaju UPGA, ni ti Ọlọrun ba le ba awọn ṣe e, lẹsẹkẹsẹ ti awọn ba ti wọle lawọn yoo tu ile-igbimọ aṣofin West ka, ti awọn yoo si ṣeto ibo tuntun fun wọn, nitori ibo ti wọn n lo lọwọlọwọ bẹẹ ki i ṣe ibo to dara, ibo ti asiko rẹ ti pari ni, o yẹ ki wọn ti dibo mi-in, ki wọn le mọ bi Akintọla lero leyin tabi ko ni. Mbadiwe yii ni lojoojumọ ni Akintọla n ti awọn UPGA mọle, ṣugbọn asiko ẹsan ti sun mọle fun un, ijọba yoo bọ lọwọ rẹ laipẹ jọjọ.
Eeyan ko ni i gbọ iru eleyii ko ma mura si ọrọ ara rẹ, ohun to jẹ ki Akintọla ati ẹgbẹ Dẹmọ rẹ ṣi maa fi gbogbo ara ja niyi. Ni ọjọ kẹrin, oṣu kejila, 1964, awọn ẹgbẹ Action Group fi ẹdun ọkan sọrọ, wọn ni ohun ti awọn n wi gan-an lo delẹ yii, wọn ni ijọba Akintọla ti sọ ilẹ Yoruba di ilu to n sinru fawọn ara ilẹ Hausa. Ẹgbẹ naa ni gbogbo ere ati iwa ti Akintọla n hu bayii ni bi yoo ti tẹ awọn aṣaaju ilẹ Hausa lọrun, ti wọn yoo le duro ti i lati le ṣeru idibo to n bọ naa. AG ni Akintọla mọ iwa awọn, nigba to jẹ ọkan ninu awọn aṣaaju awọn loun naa tẹlẹ. O mọ iwa awọn pe iwa ka maa rẹ mẹkunnu jẹ, ka maa gba lọwọ talaka lati fi tọju awọn olowo ati alapamaṣiṣẹ ọmọọba ti awọn Hausa n hu lọdọ wọn lọhun-un ni ko jẹ ki awọn ba Sardauna atawọn eeyan rẹ ṣe, ṣugbọn iwa naa ni Akintọla gba mọra bayii, koda, oun naa ti n ṣe bii wọn.
Awọn AG ni Akintọla fẹẹ ta Yoruba fun awọn Hausa ni, awọn ko si ni i gba fun un. Ọrọ naa ka Akintọla lara, nitori o mọ pe bii igba ti wọn fẹẹ ba toun jẹ nilẹ Yoruba ni. Ọjọ keji lo ti jade, to si kede pe oun naa mọ o, oun mọ pe gbogbo awọn aṣaaju AG ni wọn koriira oun. Laarin Ọja Oje, n’Ibadan, lo ti n sọ ọ. O ni ko sohun meji ti wọn fi koriira oun ju pe oun sọ fun wọn pe ko yẹ ko jẹ ẹya kan ṣoṣo (Ijẹbu) pere ni yoo maa ko gbogbo ọrọ ilẹ Yoruba si apo ara wọn. O ni awọn eeyan mẹrin pere ti wọn jẹ Ijẹbu ni wọn n ko owo awọn agbẹ gbogbo ilẹ Yoruba sapo, pe ohun ti oun wi to dija ree, ti wọn ni ki oun mu ori wa, ki oun fi ọrun silẹ, idi ti wọn ko si fi fẹran oun niyẹn. Loootọ lawọn ọmọ Dẹmọ n pariwo, ti wọn n fo soke, bi Akintọla ti n sọrọ rẹ, ṣugbọn ọpọlọpọ wọn naa lo mọ pe ọrọ naa ki i ṣe ododo, ipolongo oṣelu lasan ni.
Ọrọ naa ko yọ awọn oniroyin paapaa silẹ, bi oniroyin kan ba gbe iroyin ti ko mọdi daadaa jade, ẹsẹkẹsẹ ni wọn yoo gbe e. Ohun to ṣẹlẹ si ọkan ninu olotuu iwe iroyin Azikiwe funra ẹ ree, iyẹn West African Pilot. Wọn mu olootu yii, Herbert Unegbu, l’Ekoo, wọn ni iwe iroyin rẹ gbe iroyin kan jade, nibi ti ẹni kan ti sọrọ pe, ‘Ẹ dibo fun UPGA ki Awolọwọ le jade lẹwọn.’ Wọn ni iru iroyin bẹẹ ki i ṣe ohun to yẹ ki beba rẹ gbe jade. Kia lawọn ọlọpaa ti ṣu u rugudu, nigba ti yoo si ba ara rẹ, ninu ọgba ẹwọn ni. Bẹe naa lawọn tọọgi ẹgbẹ Dẹmọ lu ẹni kan pa ni Sango-Ọta. Amuda Anjọrin ni, wọn ni UPGA lo n ṣe. Ko jọ pe wọn fẹẹ lu u pa, o jọ pe wọn kan fẹẹ fi lilu naa halẹ mọ ọn ni. Ṣugbon wọn ti lu u ju debii pe nigba ti yoo fi de ọsibitu, o ti ku pata. Awọn ti wọn si waa lu u ti fẹsẹ fẹ ẹ.
Pẹlu gbogbo ẹ naa ni wọn dajọ idibo ọhun gan-an, wọn ni ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kejia, 1964, ni wọn yoo dibo naa, nigba naa ni wọn si tu ile-igbimọ aṣofin ka, ti wọn ni ki kaluku gba ile ẹ lọ, ko si ile-igbimọ mọ, o tun di igba ti wọn ba dibo fun awọn aṣofin tuntun. Michael Okpara, olori NCNC to tun jẹ olori UPGA, ni oun yoo tun ṣe kampeeni kaakiri West, ki wọn le mọ idi ti gbogbo wọn yoo fi jade dibo. Alaaji Dauda Adegbenro, olori ẹgbẹ AG, ti i ṣe igbakeji Okpara ninu UPGA loun naa yoo de awọn ilu kan. Kia lawọn Demọ ti mura ija, wọn gbe kọọfiu kalẹ ni Ogbomọsọ, wọn ni konile gbele, o loju ibi ti Okpara ati Adegbenro le de ni West; ẹni ba kọja aala rẹ, kele yoo gbe e. Ọrọ yii n bọrọ mi-in, kinni naa ka Okpara lara. Lo ba ni oun n lọ si Calabar, lọgba ẹwọn ti Ọbafẹmi Awolọwọ wa, ki oun lọọ fi ẹjọ Akintọla atawọn ọrẹ rẹ sun aṣaaju awọn naa, ko le fawọn nimọran lori ohun ti awọn yoo ṣe. N l’Okpara ba kọri si Calabar.