Faith Adebọla
“Mo fi tọwọtọwọ rọ awọn gomina ilẹ Yoruba lati fori kori bayii, mo si bẹ wọn lati tete gbe igbesẹ pajawiri tori a ti wa ninu ewu gidi o, ewu naa si le ba nnkan jẹ kọja aala nilẹ Yoruba laarin ọjọ diẹ sasiko yii, ta o ba wa nnkan ṣe.”
Ọrọ yii lo wa lara akiyesi pataki ti adari ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua ati sẹnetọ tẹlẹ nni, Ọjọgbọn Banji Akintoye, sọ ninu atẹjade kan fi lede l’Ọjọruu, Wẹsidee yii, lati sin awọn ọmọ Yoruba ni gbẹrẹn ipakọ lori ipenija eto aabo to gbode yii.
Atẹjade ọhun to jade latọwọ Akọwe iroyin rẹ, Ọgbẹni Maxwell Adelẹyẹ, sọ pe inu ewu nla ni ilẹ Yoruba wa bayii tori awọn Fulani agbebọn atawọn eeṣin-o-kọ’ku Boko Haram ti yi ilẹ Yoruba po, o lapa Ariwa, lati ipinlẹ Niger, ni wọn gba wọ Kwara ati Kogi, ti wọn fi kọja si ilẹ Yoruba.
Akintoye ni ta o ba ṣe nnkan kan, laarin ọjọ diẹ, awọn afẹmiṣofo naa fẹẹ maa ṣakọlu sawọn mọṣalaaṣi nla nla atawọn ṣọọṣi bii Ridiimu, Winners, Deeper Life atawọn mi-in.
Atẹjade naa ka lapakan pe:
“Apapọ awọn Fulani agbebọn, awọn Boko Haram atawọn afẹmiṣofo ọmọ ẹgbẹ ISIS ti wọn wa lagbegbe ipinlẹ Niger ti ya wọn ilẹ Yoruba o, ọna ẹyin ni wọn gba wọle lati ipinlẹ Kwara ati Kogi.
“Laipẹ yii ni orileede Amẹrika fi atẹjade kan lede, ti wọn sọ pe awọn afẹmiṣofo ọmọ ẹgbẹ ISIS ti balẹ si Guusu orileede yii, ori omi ni wọn ni wọn gba wọle, to tumọ si pe awọn ipinlẹ to sun mọ etikun wa bii ipinlẹ Eko, Ogun ati Ondo ti wa ninu ewu gidi.
“Ọrọ yii lewu pupọ, o si n beere fun pe kawọn gomina wa tete gbe igbesẹ pajawiri. Ojoojumọ ni mo n ṣaṣaro lori bii nnkan ṣe n yipada, to si n bajẹ si i nilẹ Yoruba lasiko yii, akiyesi ti mo si ṣe lo jẹ ki n maa pariwo yii.
“Ohun ti gbogbo wa mọ ni pe ohun akọkọ tawọn afẹmiṣofo yii maa n ṣe nibi ti wọn ba balẹ si ni lati maa ba awọn dukia ati nnkan amuṣọrọ ibẹ jẹ. Eyi tumọ si pe wọn le bẹrẹ si i ṣakọlu sawọn ile ijọba ati aladaani to ṣee mu yangan bii Cocoa House, n’Ibadan.
“Mo gba awọn to ni ile awoṣifila kaakiri ilẹ Yoruba lati gbe eto aabo to gbopọn kalẹ funra wọn bayii, lati maa ṣọ awọn dukia wọnyi tọsan-toru. Eyi kan awọn afara wa, awọn ile ijọba ati aladaani pataki, ileewe, ṣọọṣi ati mọṣalaaṣi gbogbo.”