Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Bii ere ori itage lọrọ naa ri fun gbogbo awọn oṣiṣẹ to wa lọfiisi gomina nipinlẹ Ekiti lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, nigba ti obinrin kan to jẹ alaga ajọ SUBEB tẹlẹ l’Ekiti, Ọjọgbọn Francisca Aladejana, ṣubu lulẹ ninu ọọfiisi rẹ, to si gbabẹ ku.
Gẹgẹ bi awọn oṣiṣẹ ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣe sọ, wọn ni Ọjọgbọn naa to jẹ oludamọran pataki si Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi, lori eto Ẹkọ, ni wọn sọ pe o wa ninu ọfiisi ni deede agogo meji ọsan, ṣugbọn o gba ipe kan lori aago rẹ, bo ṣe gba ipe naa tan lo sadeede ṣubu lulẹ.
Lọgan ni wọn ni awọn oṣiṣẹ to wa nibi iṣẹlẹ naa si gbe e digbadigba sinu ọkọ, ti wọn gbe e lọ si ileewosan, lẹyin wakati diẹ ni okiki kan pe obinrin naa ti jẹ Ọlọrun nipe.
Ṣugbọn diẹ lara awọn oṣiṣẹ ti wọn ba ALAROYE sọrọ lori iku obinrin naa sọ pe ki wọn too gbe e jade ninu ọọfiisi naa ni Purofẹsọ naa ti jade laye.
Purofẹsọ naa to ti figba kan jẹ ọga agba ileewe olukoni to wa ni ilu Ikẹrẹ-Ekiti, ko too gba ipo alaga ajọ SUBEB nipinle Ekiti.