Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Yatọ si iṣẹlẹ ina gaasi meji ọtọọtọ to paayan mẹrin l’Abẹokuta lọsẹ to kọja yii, eeyan meji mi-in lo tun dagbere faye lọsan-an ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu karun-un yii, niluu Abẹokuta kan naa. Otẹẹli ti wọn n pe ni Conference Hotel, Oke-Mosan, ni tọtẹ yii ti waye.
Alaye ti alaboojuto otẹẹli naa, Ọgbẹni Tunde Ọṣinubi, ṣe lori iṣẹlẹ ina yii ni pe ọkunrin oniṣẹ ọwọ kan lo n jo irin ẹnu ọna abawọle otẹẹli naa, afi lojiji ti ina sọ lati ara agolo ti gaasi wa ninu ẹ (Cylinder).
Ọṣinubi sọ pe ina to sọ lati ara gaasi naa lo jo ọkunrin to n jo irin mọra wọn naa, to si pa a. Ina ọhun lo tun pa ẹnikan ti wọn ko ti i mọ bo ṣe jẹ lotẹẹli naa.
Maneja otẹẹli fi kun un pe ohun to fa ina yii bawọn ṣe ro ni pe ayederu ni agolo silinda to gbana ọhun.
O ni o ṣee ṣe ko jẹ pe gbarọgudu ni, eyi ti agbara rẹ ko to lati gba gaasi sinu, to si gbana lojiji nigba ti iṣẹ n lọ lọwọ.
O kilọ fawọn araalu atawọn oniṣẹ ọwọ lati ṣọra fun gaasi ti wọn n ra lasiko yii, nitori ayederu silinda ti gbode kan.
Alaboojuto ọtẹẹli yii ko ṣai ba ẹbi awọn ẹni to padanu ẹmi wọn yii kẹdun, o ni ki i ṣe pe otẹẹli awọn mọ-ọn-mọ ṣe wọn ni ṣuta, ohun ti yoo ṣe ni ko ni i gbọ ni.
Otẹẹli nla ni Conference Hotel, gomina tẹlẹ nipinlẹ Ogun, Ọtunba Gbenga Daniel lo si ni in.