Awọn ọlọpaa ti mu ọkunrin ọmọ orilẹ-ede Uganda kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Musilumu Mbwire, ẹni ọdun mẹrindinlaaadọta (46) ti wọn lo dumbu awọn ọmọ ẹ ọkunrin meji. Miliọnu mẹrin naira lo ni ọga oun ṣẹleri lati foun boun ba le pa awọn ọmọ naa, toun si gbe ẹjẹ wọn wa, o lohun to jẹ koun dumbu wọn bii ẹran niyẹn.
Ninu oṣu kẹta, ọdun 2021 yii, ni ọkunrin naa huwa ika ọhun gẹgẹ bo ṣe wi. Abule Jiira, lapa ibi ti wọn n pe ni Bbaale, ni Uganda, loun atawọn ọmọ naa n gbe.
Mbwire ṣalaye fawọn ọlọpaa lẹyin oṣu keji ti aṣiri tu, o ni ọga toun n ba ṣiṣẹ lo fẹẹ ṣoogun owo, o si ṣeleri lati foun ni miliọnu mẹrin owo ilẹ Uganda, boun ba le pa awọn ọmọ oun ọkunrin meji, Latif Kamulasi; ọmọ ọdun meje, ati aburo ẹ, Sahum Baizambona, to jẹ ọmọ ọdun mẹta.
O loun gba lati pa awọn ọmọ naa nitori owo yii, oun si ko wọn lọ sinu igbo, nibi toun yanju wọn si. Ṣugbọn ọga ko ti i fun oun lowo naa tan gẹgẹ bo ṣe wi, o ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan owo Uganda lo ṣi foun ninu adehun tawọn ṣe.
Ọga rẹ to ni o bẹ oun niṣẹ ti ta ku ṣa, o loun ko ba Musilumu sọ ohun to jọ bẹẹ, irọ lo pa mọ oun. Ṣugbọn awọn mejeeji lawọn ọlọpaa ko, wọn si ti wa lahaamọ bayii, wọn yoo ko wọn lọ sile-ẹjọ.
Musilumu tilẹ mu wọn lọ sibi to sin ọmọ ọdun meje naa si, oun naa lo n fi sọbiri wa yẹẹpẹ ibẹ, to n ko eyi to jẹra ku lara ọmọ naa jade. Wọn ni ko niṣoo nibi to sin ọmọ ọdun mẹta rẹ si, ṣugbọn ko mọbẹ mọ, irọ ni wọn ba ni gbogbo ibi to mu wọn lọ.