Awọn Boko Haram kọ lu gomina, diẹ lo ku ki wọn mu un

Ọlọrun lo yọ Gomina Ipinlẹ Borno o. Gomina Babagana Zulum n pin ounjẹ kaakiri awọn adugbo ti awọn afẹmiṣofo yii ti bajẹ ni ipinlẹ naa, ti wọn si ti sọ awọn eeyan ibẹ di alaini ati alarinkiri ni. Ohun to fa eyi ni pe awọn ṣọja ti fi i lọkan balẹ, wọn ni ni gbogbo ipinlẹ Borno bayii, lati Maiduguri titi de awọn ilu to ku nibẹ, ko si ibi kan bayii ti awọn Boko Haram ku si mọ, gbogbo wọn lawọn ti le lọ.

Ohu to mu ki Gomina Zulum maa kiri ree, to si  n ha ounje fawọn isansa naa ti won ko lẹni kan. Ṣugbọn ni Ọjọruu, oun atawọn eeyan rẹ kọri si ọna ilu Baga, nibi ti awọn Boko Haram yii ti gba lọwọ ijọba Naijiria lọjọ to ti pẹ, to jẹ awọn gan-an ni wọn n ṣe ijọba apa ibẹ. Ohun to jẹ ko fẹẹ lọ naa ni pe awọn ọga ṣọja ti sọ fun un pe ko si Boko Haram eyọ kan ni Baga mọ, ko lọ sibi to ba wu u ni. Ṣugbọn bi wọn ti de itosi ilu naa ni iro ibọn bẹre si i dun, awọn Boko Haram si ya bo wọn bii eṣu. Bi ko jẹ ere buruku ti awọn to n gbe Gomina naa tete sa pada pẹlu ibọn tawọn ẹṣọ rẹ n yin soke, wọn ba mu Gomina yii ṣinkun ni. Ọlọrun lo yọ ọ.

Ọrọ naa ka Gomina Zulum lara debii pe nigba to jaja yọ, baraaki awọn ṣọja ti ko ju maili mẹrin si Baga yii lọ lo gba lọ, o lọọ ba wọn ja nibẹ ni. O fibinu sọrọ bayii pe, ‘Ẹyin lẹ sọ fun mi pe ko si Boko Haram nibi yii mọ. Bo ba je ko si Boko Haram, awọn wo lo kọ lu wa yii o!’ Ko ti i sẹni to le fun un lesi ninu awọn ọga ologun.

 

One thought on “Awọn Boko Haram kọ lu gomina, diẹ lo ku ki wọn mu un

Leave a Reply