Olu-Theo Omolohun Oke-Ogun.
Olobo kan ti ta awọn agbofinro ati ijọba ipinlẹ Ọyọ pe awọn ẹgbẹ kan lara ẹya Fulani darandaran ti wọn ti n gbe niluu Igangan, nijọba ibilẹ Ariwa Ibarapa, nipinlẹ Ọyọ, lo n da omi alaafia agbegbe naa ru lati ọjọ yii, wọn ni mẹta lara ọmọ Seriki Fulani, Alaaji Saliu AbdulKadir, lo wa lara wọn, ti wọn ṣi ṣẹku sinu igbo agbegbe naa.
Lara awọn Fulani ti wọn darukọ wọn pe awọn ni wọn ṣi fori mulẹ sinu igbo ti wọn n ṣe awọn agbẹ ni ṣuta lasiko yii ni Ọgbẹni Maman Saliu, Ibrahim Saliu, ati Aliu Saliu, wọn lawọn mẹtẹẹta yii, ọmọ Seriki ti Sunday Igboho ṣigun le lọ kuro niluu Igangan lọjọsi ni wọn.
Awọn mi-in ti wọn ṣi wa ninu igbo naa pẹlu wọn ni Mamudu Abagun lati ilu Iganna, Seriki Warago lati ijọba ibilẹ Itẹsiwaju, nipinlẹ Ọyọ, Mumini Saleh to ti figba kan jẹ Alaga ẹgbẹ Miyetti Alhah nilu Abeokuta, Lawal Galadima ati Hajia Amina ti wọn ni gbogbo wọn n ṣe agbodegba fun Seriki Igangan, bo tilẹ jẹ pe ko si lagbegbe ọhun mọ.
Wọn ni gbogbo awọn ta a darukọ wọn yii ni wọn lọọ fẹhonu han lọfiisi awọn ọtẹlẹmuyẹ niluu Ibadan pe awọn ko fara mọ igbesẹ tawọn kan n gbe lati yọ Alaaji Kadiri Saliu nipo gẹgẹ bii Seriki Fulani ipinlẹ Ọyọ, ipo ti ọkunrin naa ti wa ki wọn too ṣi i nidii kuro niluu Igangan.
Wọn lawọn eeyan wọnyi mọ nipa iwa ijinigbe, ipaniyan ati fifi maaluu jẹko to n waye lagbegbe Ibarapa, awọn eeyan agbegbe naa si ti kọwe sileeṣẹ ọlọpaa lati ṣiṣẹ itọpinpin to lọọrin lori wọn.
Bakan naa ni wọn lawọn ẹṣọ Amọtẹkun ati awọn OPC ti fọwọ sowọ pọ lati fi pampẹ ofin gbe awọn afurasi ọdaran wọnyi, ati lati fa wọn le awọn agbofinro lọwọ.
A gbọ pe gbogbo ọna ni Seriki ti wọn ti le danu naa n ṣan lati pada si agbegbe Ibarapa, wọn lo sọ pe toun ko ba le gbe ilu Igangan, oun le wa nitosi ilu naa tabi lagbegbe mi-in, tori awọn oko ati dukia oun kan ṣi wa toun ko fẹẹ padanu wọn.
Ẹni to jẹ ki ALAROYE gbọ nipa ọrọ yii sọ pe iṣẹ iwadii nla lawọn ṣi n ṣe lọwọ, awọn aṣiri pupọ si ti n tu sawọn lọwọ.