Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ki ibaṣepọ to gun rege, ti yoo si mu ọrọ aje, nnkan amayedẹrun, eeto aabo, ayika, ipese ounjẹ atawọn nnkan mi-in gbooro si le waye, ipinlẹ Ogun ati ipinlẹ Eko ti tọwọ bọwe adehun (Memorandum of Understanding)
Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu karun-un, ọdun 2021, ni eyi waye niluu Abẹokuta, nigba ti Gomina Dapọ Abiọdun gbalejo Gomina Babajide Sanwo-Olu ti ipinlẹ Eko, pẹlu awọn ikọ to ba gomina naa kọwọọrin wa sile ijọba l’Abẹokuta.
Ninu ọrọ rẹ, Gomina Abiọdun ṣalaye pe ajọṣepọ yii yoo mu irẹpọ waye laarin Ogun ati Eko to jẹ alamulegbe rẹ, awọn ọrọ to ba kan ipinlẹ mejeeji yoo si ṣee maa gbe yẹwo lasiko kan naa lai pa eyikeyii wọn lara. Eyi yoo mu anfaani to pọ ba awọn olugbe ilu mejeeji gẹgẹ bi Gomina Abiọdun ṣe wi.
O waa rọ awọn onileeṣẹ aladaani lati sowo pọ pẹlu ijọba ipinlẹ mejeeji, ki idagbasoke nipa idasilẹ ileeṣẹ le wa si imuṣẹ.
Ṣaaju ni Gomina Babajide Sanwo-Olu ni tiẹ ti ṣapejuwe ajọṣepọ yii gẹgẹ bii eto kan ti yoo yi bi nnkan ṣe n wa tẹlẹ pada, ti yoo tun mu Eko gbayi si i ju bo ṣe wa tẹlẹ lọ.
Sanwo-Olu sọ pe ọna to daa ju lati goke agba ni sisowọ-pọ pẹlu ara ẹni bii eyi, gẹgẹ bi wọn ṣe n ṣe kaakiri agbaye. O ni laipẹ ni ere to wa nidii ajọṣepọ yii yoo bẹrẹ si i jade.