Bii ogoje eeyan, ninu eyi ti ọpọ wọn jẹ obinrin atawọn ọmọ keekeeke ni wọn si n wa ninu ijamba ọkọ oju omi kan to ṣẹlẹ ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii ni apa Oke-Ọya. Ipinlẹ Kebbi ni wọn ni awọn ero inu ọkọ oju omi naa n lọ lati ipinlẹ Niger.
Niṣe ni ọkọ oju omi naa to gbe awọn ero bii ọgọjọ (160) deede ṣẹ si meji laarin agbami gẹgẹ bi iroyin BBC ṣe sọ ọ, to si rọ gbogbo ero to wa ninu rẹ da sinu omi. Awọn obinrin atawọn ọmọde ni wọn sọ pe wọn pọ ju ninu awọn to re somi naa.
Bii ogun eeyan pere ni wọn ti ri yọ ninu wọn, nigba ti wọn ri oku ẹni kan yọ.
Titi di ba a ṣe n sọ yii ni awọn omuwẹ ṣi n wa awọn eeyan to ku ninu omi naa.