Ko ti i sẹni to le sọ ohun to fa ijamba ina nla kan to ṣẹlẹ ni ọja ti wọn ti n ta paati mọto niluu Eko ti wọn n pe ni Ladipọ Market ni ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii. Ohun ti awọn ara agbegbe ti ọja naa wa ni Mushin kan ri ni pe ina nla sọ ninu ọja nla yii. Ki wọn si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, ina naa ti n jo ajoran, o si ba awọn ṣọọbu ati ọja olowo iyebiye to wa nibẹ jẹ. Ọpọ ṣọọbu atawọn ọja to wa nibẹ lo jona gburugburu.
Bo tilẹ jẹ pe awọn panapana lọ sibẹ, nnkan ti bajẹ patapata ki wọn too de ọhun.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ajọ pana, Amodu Shuabu, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o si rọ awọn eeyan agbegbe naa lati gba alaafia laaye.