Faith Adebọla
Ọsibitu aladaani kan niluu Abuja ni wọn sare gbe gbajugbaju oniroyin ajafẹtọọ nni, Ọmọyele Ṣoworẹ, lọ, latari bi agolo afẹfẹ tajutaju tawọn ọlọpaa yin lu u ṣe ṣee leṣe nibi itan rẹ.
Owurọ ọjọ Aje, Mọnde yii, niṣẹlẹ ọhun waye nigba tọkunrin naa atawọn ẹlẹgbẹ rẹ n ṣe iwọde ta ko ijọba Buhari lagbegbe Unity Fountain, niluu Abuja.
Lajori iwọde naa ni pe ki Aarẹ Muhammadu Buhari fipo silẹ, ko yẹba, wọn ni iṣakoso rẹ n fara ni araalu, itajẹsilẹ ati aabo to mẹhẹ yii si ti de gongo.
Agbẹjọrọ ọkunrin naa, Inibehe Effiong, sọ pe ọlọpaa-binrin kan lo yin tiagaasi (teargass) lu Ṣoworẹ ti kinni naa si fa itan rẹ ya.
Ninu fidio kan ti lọọya naa fi lede lori atẹ ayelujara, o fi ibi ti Ṣoworẹ ti ṣeṣe han, o si kọ ọ sabẹ fidio naa pe:
“Awọn ọlọpaa ti ṣe Ọmọyele Ṣoworẹ leṣe o, niṣe ni wọn yinbọn, ti ọlọpaa-binrin kan si yin gaasi tajutaju lu wọn. Itan rẹ lo ju agolo gaasi naa ba. A ti gbe e lọọ ọsibitu kan fun itọju. Ṣoworẹ gan-an ni wọn fẹẹ kọ lu, wọn fẹẹ pa a ni.”
Bakan naa ni Ṣoworẹ kọ ọ sori ikanni ayelujara rẹ pe: “Wọn ti ṣe mi leṣe o, ọlọpaa-binrin kan, ACP Atine, lo yin nnkan ba mi, to si fa ara mi ya. Iwaju Unity Fountain l’Abuja la duro si ni tiwa, ki wọn too waa kọ lu wa o.
“Ti mo ba ku, ẹ ma sinmi ija yii o, Buhari gbọdọ lọ dandan ni.”
Awọn kan ti ọrọ naa ṣoju wọn sọ lori atẹ ayelujara pe yatọ si afẹfẹ tajutaju ti wọn da bolẹ, wọn ni niṣe ni awọn ọlọpaa tun ṣina ibọn fawọn to n ṣewọde ọhun.