Ọwọ tẹ Nasiru to n ṣe bii were ni Saki, aṣe gbọmọgbọmọ ni

Olu-Theo Omolohun, Oke-Ogun

Ọwọ palaba ọkunrin kan, Nasiru, ti wọn lo n dibọn bii alarun ọpọlọ, ṣugbọn ti wọn lo fẹẹ ji ọmọ ọdun meji kan gbe niluu Ṣaki, ti segi.

Nasiru lọwọ tẹ ninu ọja to wa laduugbo Ajegunlẹ, niluu Ṣaki, l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, lakooko to fẹẹ ji ọmọde naa gbe lẹgbẹẹ iya rẹ.

Gẹgẹ bi awọn to fi iṣẹlẹ naa to wa leti ṣe sọ, wọn ni ẹyin iya ọmọ naa lọmọ ọhun ti wa latigba ti wọn ti de lati ọja lọjọ naa, niṣe ni iya rẹ pọn ọn titi to fi to igba wosiwosi rẹ tan.

Ko pẹ to patẹ ọja rẹ tan lawọn onibaara n de lọkọọkan ejeeji, nigba to si ya ti awọn onibara ti pọ niwaju rẹ lo fa a to fi sọ ọmọ naa kalẹ, wọn lo rọra tẹ ẹ sẹgbẹẹ ibi ti ijokoo rẹ wa, ko le raaye da awọn onibaara naa lohun.

Wọn ni bi obinrin naa ṣe da wọn lohun tan lo ṣakiyesi ibi to tẹ ọmọ rẹ, Aliya si, lọmọ ọhun ti poora.

Eyi lo mu ki obinrin naa figbe ta, to si keboosi sawọn ero inu ọja pe ẹnikan ti gbe ọmọ oun o, kawọn abiyamọ aye gba oun.

Kia ni wọn lawọn ọkunrin atobinrin ti fọn ka saarin ọja ati igboro ilu, ti kaluku bẹrẹ si i wa ọmọ tirẹ, bẹẹ ni wọn n wa ibi ti wọn le salabade ọmọ ti wọn ji gbe ọhun.

Lẹyin bii ọgbọn iṣẹju lariwo ta pe wọn ti ri ọmọ naa lọdọ ‘were’ kan to n jẹun lọwọ lori aakitan nla to wa niluu naa, eyi lo mu kawọn gende kan sun mọ Nasiru, wọn ba ọmọ naa lẹgbẹẹ rẹ, ni wọn ba gbe ọmọ ọhun, wọn si wọ oun naa tuuru.

A gbọ pe niṣe lo kọkọ n ṣe bii ẹni ti ko gbọran, ti ọpọlọ rẹ ko pe, ṣugbọn lẹyin ti wọn ti din dundu iya diẹ fun un, o lahun, o jẹwọ pe Nasiru lorukọ oun, ọmọ bibi orileede Bẹnnẹ si loun.

Wọn lọkunrin naa ko ri alaye kankan ṣe nigba ti wọn bi i leere pe bawo lọmọ ṣe de ẹgbẹ rẹ lori aakitan lati ọja ti iya rẹ tẹ ẹ si, eyi lo mu ki wọn taari ọkunrin naa sọfiisi awọn ẹṣọ Amọtẹkun to wa nitosi. Wọn lawọn Amọtẹkun ni yoo fa a le awọn agbofinro lọwọ lẹyin iwadii wọn.

 

 

 

Leave a Reply