Bi ibanujẹ ba dapọ mọ ayọ, arojinlẹ lori iṣẹlẹ bẹẹ lo le jẹ keeyan maa dupẹ. Gẹgẹ bii ẹlẹran ara, ọpọ igba leeyan yoo maa ro arokan lori ibanujẹ naa, eeyan yoo si fẹrẹ maa da Ọlọrun lẹbi lori ohun to ṣẹlẹ si i.
Bẹẹ lo ṣi n ri lọwọlọwọ fun baale ile kan to wa lati ipinlẹ Delta, Ọgbẹni Ediri Voghor. Iyawo ẹ, Abilekọ Chika Anthonia Voghor, lo ku lẹyin ọjọ kẹta to bi ibeji fun un, bẹẹ, ọdun kejidinlogun (18) ree ti wọn ti jọ n sunkun ai rọmọ bi, ti wọn fomije bẹ Oluwa pe ko da awọn lohun, kawọn naa tiẹ di ọlọmọ.
Gẹgẹ bi Ọgbẹni Voghor ṣe ṣalaye fun iwe iroyin TRIBUNE, o ni lati ọdun 2002 tawọn ti ṣegbeyawo, iyawo oun ko loyun ri, bawọn ba si lọ sọsibitu, awọn dokita yoo sọ pe ko si kinni kan to n ṣe awọn mejeeji, ara awọn pe lati loyun, ṣugbọn niṣe loyun ṣaa kọ ti ko wa.
Asiko kan wa ti wọn ni iju lo n daamu Chika gẹgẹ bii alaye ọkọ ẹ, koyun le baa duro, wọn ṣiṣẹ abẹ fun un, ara rẹ si ya, ṣugbọn oyun ko tori ẹ wa naa.
Afi lọdun 2019, ọdun to kọja, ti oyun duro si i lara fun igba akọkọ. Tọkọ-taya ko tiẹ kọkọ gbagbọ pe oyun ni, afi nigba ti ayẹwo fidi ẹ mulẹ, ti ikun Chika si n tobi si i loṣooṣu. Aṣe ibeji lo wa nibẹ, aṣepe si ni iṣẹ Eledumare, ọkunrin kan, obinrin kan lawọn ibeji naa.
Ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹfa, ọdun 2020, lọjọ ikunlẹ pe, iṣẹ abẹ ni wọn ṣe fun obinrin naa nitori iju ti wọn ni wọn ti gbe kuro ninu rẹ ri, awọn ọmọ meji ti wọn wa lalaafia si balẹ gudẹ lẹyin iṣẹ abẹ ọhun. Ni inu gbogbo eeyan ba n dun nile wọn, gbogbo famili atawọn ti ko tiẹ mọ wọn ri ni wọn waa wo ohun ti Oluwa ṣe fun tọkọ-taya Voghor to fọdun mejidinlogun wa ọmọ.
Aṣe ayọ naa ko ni i dalẹ tan, ọjọ keji ti Iyaabeji bimọ ni wọn lo ni oun ko le mi daadaa, ara oun ko si ṣe daadaa, bi wọn ṣe ba a pe nọọsi wa niyẹn, iyẹn si fun un nitọju pajawiri lara rẹ ba ya.
Afi bo ṣe tun di loru ọjọ naa ti wọn ni nnkan yiwọ. Niṣe ni wọn kọkọ ni ẹjẹ ko to lara Chika, wọn tun ni ifunpa rẹ walẹ, o ti kere si bo ṣe yẹ ko ri. Awọn dokita ṣaa bẹrẹ si i wa ọna abayọ soun to n ṣe obinrin naa, wọn ni ẹjẹ n da lara ẹ lati inu ni, ko han sita.
Nigba ti yoo fi di aarọ ọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹfa, ti i ṣe ọjọ kẹta to bimọ, ni Chika Anthonia Vogha dagbere faye, o si da awọn ẹjẹ ọrun to fọdun gbọọrọ wa silẹ, obinrin naa gba ọrun lọ.
Bi wahala ṣe de niyẹn o, ti ibanujẹ bori ayọ, ọkọ ko ri iyawo ẹ mọ, to si waa jẹ pe ẹgbọn Chika, Akachukwu Scholastica, ni wọn ko awọn ibeji naa fun pe ko maa tọju wọn. Iyẹn paapaa ko mọ bi yoo ti ṣe awọn ọmọ ọhun si gẹgẹ bo ṣe wi, nitori o ni ko si boun yoo ṣe tọju wọn ti yoo jọ tẹni to gbe wọn sikun foṣun mẹsan-an, lẹyin to wa wọn titi ti ko ri wọn.